Mo ti dé láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà, ojú ẹ̀mí mi ni mo máa parí sáà mi – Akeredolu

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Olawale Abolade

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti sọ pe oun yoo bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ ni bayii to pada de si Naijiria lati irinajo to lọ latari aisan to ba a finra.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Richard Olatunde fi lede, o ni Akeredolu ti ṣe ipade pẹlu awọn alabaṣiṣẹ rẹ, o si ti ṣetan lati pada sẹnu iṣẹ ni kankan.

Atẹjade naa ni: “Ni kete to de lo ṣe ipade pẹlu awọn ti ọrọ iṣẹjọba kan lati ipinlẹ Ondo nilu Ibadan to de si.”

“Lara awọn to wa nibi ipade naa ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin, ti agbẹnusọ wọn ko sodi....”

Awọn mii to tun wa nibi ipade ọhun ni iyawo rẹ, Betty Akeredolu, awọn aṣoju ẹgbẹ oṣulu APC nipinlẹ Ondo, atawọn eeyan mii.

Gẹgẹ bi ohun ti Richard Olatunde sọ, ibi ipade naa ni Akeredolu ti fi iwe pe oun ti pada sẹnu iṣẹ le agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin, Oladiji Olamide lọwọ, bẹẹ naa lo tun fun igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa ni ẹda iwe ọhun.

Akeredolu sọ nibi pade naa pe “lagbara Ọlọrun, mo ti pada de bayii o, mo maa wa laaye titi ti mo maa fi pari saa mi lori oye.”

“Mo fẹ sọ fun yin pe mo ti pada de, mo maa bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ, iwe pe mo ti pada sẹnu iṣẹ ree.”

Nnkan bii oṣu mẹta ni Akeredolu lo lorilẹ-ede Germany lati lọ gba itọju lẹyin to dubulẹ aisan, ti igbakeji rẹ Lucky Aiyedatiwa si dele de e.

Akeredolu padà sílé lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tó ti lọ gbà ìtọ́jú lókè òkun

Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Betty Anyanwu-Akeredolu/X

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti pada sile lati oke okun lẹyin isinmi oṣu mẹta to fi lọ tọju ara rẹ.

Nigba ti aarẹ mu Akeredolu ni o rinrin ajo lọ si orilẹede Germany fun itọju ara rẹ.

Olori ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Họnọrebu Wole Ogunmolasuyi sọ fawọn akọrin pe Ile rẹ to wa niluu Ibadan ni Akeredolu de si ni Ọjọbọ.

Aye gomina, Betty Akeredolu lo kọkọ sọ nipa ipadabọ Akeredolu si Naijiria lẹyin to fi aworan ibi ti Aketi ti joko ninu ọkọ ofurufu sori oju opo ayelujara X pẹlu akọle ile koko tangbe.

Ọjọ Ẹti ni a gbọ pe igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ondo atawọn loyeloye yoo lọ ṣe abẹwo si gomina nile rẹ.

Bakan naa ni adele gomina, Ọgbẹni Lucky Ayedatiwa yoo jiṣẹ iriju rẹ fun Akeredolu lọjọ Ẹti yii kan naa.

Ohun ti a gbọ nipe Akerdolu yoo sinmi nile rẹ niluu Ibadan fun igba diẹ ki o to pada sẹnu iṣẹ ni ipinlẹ Ondo.

Ṣaaju ni Akeredolu ti sọ fun ile igbimọ aṣofin nipa irin-ajo rẹ ti o si gbe agbara fun igbakeji rẹ pe ki o dele fun oun.

Lọsẹ to lọ ni akọwe iroyin fun gomina, Ọgbẹni Richard Olatunde sọ pe Akeredolu si n gba itọju loke okun, ati pe yoo pad ade laipẹ.

Ọgbẹni Olatunde sọ nigba naa pe gbogbo eeyan ni yoo gbọ nigba ti gomina ba pada si Naijiria lati orilẹede Germany to ti lọ gbatọju.