Àwọn adigunjalè ṣekúpa èèyàn mẹ́wàá lásìkò ìkọlù sí Báǹkì

Oríṣun àwòrán, Others
Eeyan mẹwaa lo dero ọọrun a re ma bọ lasiko ti awọn adigunjale ṣekọlu si awọn Ileeṣẹ Banki kan ni agbegbe kan ni ijọba ibilẹ Otukpo nipinlẹ Beune.
Ikọlu naa lo waye lọjọ Ẹti, ti ọlọpaa mẹta si wa lara awọn jẹ pe Ọlọrun.
Gẹgẹ bi Ileeṣẹ iroyin abẹle Channels TV ṣe gbe sita, wakati meji ni awọn adugunjale naa fi sọsẹ, ti ko si ẹsọ alabo kankan to diwọn lọwọ lasiko naa.
Oṣojumikoro to ba ileeṣẹ iroyin abẹle sọrọ ni Ileeṣẹ Banko marun un ọtọtọ ni awọn adigunjale naa kọlu, to si jẹ pe pupọ awọn banki lo kọju si ileeṣẹ ọlọpaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Oṣojumikoro sọ fun Premium Times pe; “Awọn adigunjale sọsẹ ni awọn banki ni Otukpo lọjọ Ẹti, ti wọn si sina bolẹ. Wọn ṣekupa eeyan mẹwaa.”
Bakan naa ni awọn adigunjale naa ṣe ikọlu si ileeṣẹ ọlọpaa to jẹ ti abẹle nipinlẹ naa.
Ni bi ago mẹrin abọ ọjọ Ẹti ana ni isẹlẹ naa waye ti wọn si wọle si awọn banki yii pẹlu ọkọ Hilux ati awọn ọkọ ayọkẹlẹ miiran, ti wọn si mu awọn ohun ija bi ibọn lọwọ.
Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Beune, Sewuese Anene fidi isẹlẹ naa mulẹ sugbọn ko ti sọrọ pupọ lori ikọlu naa.
Bakan ni awọn to farapa nibi isẹlẹ ti wa ni ile iwosan ni bi ti wọn ti n gba itọju.












