Ìròyìn òfegè ni ìròyìn tó ní mo ra ọkọ̀ fún Baba Mohbad - Cute Abiola pariwo síta

Aworan Cute Abiola, Mohbad ati Joseph Aloba

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajugbaja adẹrinposonu, AbdulGafar Abiola ti ọpọ mọ si Cute Abiọla ti bu ẹnu atẹlu iroyin kan to jade sori ayelujara pe o ran ọkọ ayọkẹlẹ tuntun fun Joseph Aloba, baba olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad,

Cute Abiola ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara, o salaye pe irọ ni iroyin naa, to si sapejuwe rẹ gẹgẹ bi iroyin ofege nitori pe oun ko ra ọkọ ayọkẹlẹ fun Baba Mohbad lati tu inu lori iku ọmọ rẹ gẹgẹ bi iroyin naa ṣe gbe jade.

Iroyin naa ni “ Lawyer Kunle ṣẹṣẹ ra ọkọ ayọkẹlẹ Lexus tuntun toto ogun milionu fun baba Mohbad.”

Aworan lati oju opo Cute Abiola

Oríṣun àwòrán, Instagram/Cute Abiola

Lawyer Kunle bọ sori opo ayelujara Instagram rẹ lati bu ẹnu atẹlu iroyin naa, to si jẹ ko di mimọ pe oun ko fi igba kan ni erongba lati ọkọ fun Baba Mohbad paapa pe oun ko ni ibaṣepọ kankan pẹlu rẹ.

“Tani ẹyin eeyan yii tori Ọlọrun? N ko ra ọkọ ayọkẹlẹ fun Baba Mohbad , n ko si ṣe ileri pe ma ra ọkọ fun ẹnikẹni.

“Kilode ti awọn eeyan fẹran lati ma gbe iroyin ofege jade lai ṣe iwadii to tọ. Ra ọkọ ayọkẹlẹ fun Baba Mohbad fun kini, ti ẹ si mọ pe ko ki n pẹ ṣe ifọrọwerọ sita”

Aworan lati oju opo Cute Abiola

Oríṣun àwòrán, Instagram/Cute Abiola

Ki lo sẹlẹ saaju?

Ọjọ kejila oṣu kẹsan an ọdun 2023 ni iroyin iku Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad, gbajugbaja olorin takasufe gba ori ayelujara, to si ba ọpọ paapa awọn oloufẹ rẹ ninu jẹ.

Kaakiri orilẹede Naijiria ni iwọde ati ifẹhonuhan ti waye, ti wọn si n bere fun idajọ ati afihan ohun to ṣekupa Mohbad.

Mọlẹbi ti kọkọ sin oku oloogbe naa lọjọ keji to jade laye sugbọn Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko kede pe awọn yoo bẹrẹ iwadi, eyi to jẹ ki wọn hu oku naa jade fun ayẹwo.

Ọpọlọpọ afurasi lo ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa, ti fi mọ gbajugbaja olori takasufe, Azeez Fashola, ti ọpọ mọ si Naira Marley.

Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Eko, Idowu Owohunwa salaye pe abajade ileesẹ ọlọpaa lori iku Mohbad fihan abẹrẹ mẹta ọtọọtọ ti nọọsi fun Mohbad lo jẹ ki iku rẹ ya.

“Lọwọ yii, awọn afurasi marun un ni a ti mu, ti wọn si ti wa ni ahamọ wa bayii lori iku oloogbe naa.”

Lara awọn to ti wa ni atimọle ni “nọọsi to fun ni abẹrẹ mẹta ọtọtọ, eyii ti o wa lara nnkan to gbẹmi rẹ.”

“Nọoṣi naa gan ni ojulowo afurasi wa.”

“O jẹwọ pe awọn abẹrẹ ti oun fun oloogbe naa lo fa nnkan to pada yọri si iku Mohbad.”