Igi Àràbà ya lulẹ̀ n'Ilorin, èèyàn méjì kú lójú ẹsẹ̀, márùn-ún farapa yána-yàna

Ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ńlá ló waye ni òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtalélógún oṣù Kẹwa ọdun 2023 nigba ti igi Araba nla kan ya lulẹ, to si wó pa èèyàn méjì.
Bakan naa, èèyàn márùn-ún míràn lo fara gbọgbẹ lorisirisi nibi isẹlẹ naa eyi to waye ni deede aago mẹjọ aarọ.
Nigba ti BBC Yoruba de ibi ti isẹlẹ naa ti waye ni Oke-Andi, Kulende nilu Ilorin, awọn ti isẹlẹ naa soju wọn salaye ohun to fa sababi rẹ.
Wọn ni awọn eeyan kan lo duro labẹ igi ọhun lati maa duro de ọkọ ero ti wọn yoo wọ lọ sibi isẹ ati ibudo itaja wọn.
Iṣẹlẹ naa si lo sọ awọn eniyan agbegbe ọhun sinu laasigbo nla nitori bi igi Araba naa se sadede ya lulẹ, ni eniyan meji jade laye lẹsẹkẹsẹ.
Awọn marun un yoku to fara pa si n gba itọju ni ile iwosan bayii.

"Kẹkẹ Maruwa kan duro si abẹ igi Araba naa lati gbe ero, apa igi kan to ya lulẹ ja lu u lori, gbogbo gilaasi waju rẹ si fọ"
Awọn ti isẹlẹ naa soju wọn sọ wi pe, ojo ko rọ, afẹfẹ ko fẹ bẹẹ si ni iji ko ja nigba ti isẹlẹ naa waye, eyi ti a le sọ pe o se okunfa bi igi Araba naa se wo lulẹ.
Sugbon wọn ni sadede ni awọn ri ọwọ nla latara igi araba naa to ya le awon eniyan lori.
"Kẹkẹ Maruwa kan naa duro si abẹ rẹ lati gbe ero, apa kan ja lu u lori, gbogbo gilaasi waju rẹ si fọ, amọ, dẹrẹba ati awọn ero inu rẹ moribọ.
"Loju ẹsẹ ni a fi ọrọ naa to ìjọba leti, wọn si gbe ọkọ itọju aisan pajawiri, anbulansi, wa lati ko awon eniyan naa lọ si ile iwosan fun itọju.
"Bakan naa ni ajọ ton ri si ọrọ ayika ati ọrọ ilera naa ti wa wo ohun to sẹlẹ , awon naa si ti kopa tiwọn lati doola ẹmi awọn eeyan to farapa.
Awọn ọrọ ayika naa si ni awọn si tun n tiraka lati ri daju pe iru isẹlẹ ibi yii ko waye mọ.
"Igi Araba naa ti di abami igi, a si ma n ba ẹbọ ni abẹ rẹ loorekore, o ti gbabọde"
Awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn tẹsiwaju pe "Mẹta ni igi Araba nla to wa ni agbegbe yìí sugbọn eleyi nikan ni o ku.
Meji ti di wiwo lulẹ, ohun lo fa a ti a fi gba àwọn rẹgi rẹgi lati rẹ eleyi naa ni lati mu ki ọkan gbogbo eniyan lee balẹ ladugbo."
Ọ̀rọ̀ àwọn ará àgbègbè ṣe ọ̀ọ̀tọ̀ lorí igi náà, àwọn kan pè é ní abàmì, àwọn kan sì tún pè é ní igi àlàáfíà.
Awọn kan sọ pe igi naa ti di abami igi, ti wọn si ma n ba ẹbọ ni abẹ rẹ loorekore, to si seese ko ti gba abọde.
Awọn miran ni bẹẹ kọ, wọn ni o jẹ igi alaafia, to si n se ibojì fun awọn eniyan lati gbafẹ.
Wọn fi kun un pe, amuwa Ọlọrun ni ohun to sẹlẹ, ti ẹda kankan ko si lee sọ ohun to se okunfa ayafi Ọlọrun fun ra rẹ.

Wọn ri iho nla ninu igi Araba naa nigba ti wọn rẹ lulẹ, wọn ni o seese ko jẹ ile awọn bọra inu igi ni
Awon olugbe agbegbe Oke-Andi, Kulende nilu Ilorin naa ko se meni, ko se meji, n se ni wọn gba awọn rẹgi rẹgi, wọn si rẹ iyoku igi naa lulẹ patapata.
Amọ kayefi nla lo jẹ pẹlu bi wọn ṣe ba iho nla ninu igi ọhun nigba ti wọn rẹ lulẹ tan.
Bi awọn eeyan kan se n sọ wipe awọn ọ̀rọ̀ igi lo n gbe ibẹ, to si fi inu iho igi naa se ile, awọn si lo seese ko se okunfa isẹlẹ ibi naa.
Ni awọn eeyan miran sọ pe awọn kokoro lo ti jẹ inu igi naa, ti wọn si gbẹ iho nla sinu rẹ, eyi ti ko mu ko ni agbara mọ lati da duro, lo se wo lulẹ.

Ile iwe ni mo n lọ, mo n duro de ọkọ ero ti yoo gbe mi, nigba ti igi Araba sadede ya le wa lori - Fatimoh Jamiu
BBC Yoruba sabẹwo si ile iwosan Araolu nibi ti ọkan ninu awọn to farapa nibi iṣẹlẹ ọhun, Jamiu Fatimoh ti n gba iwosan.
Jamiu Fatimoh, tii se akẹkọ Grand Plus College of Education, Offa Garage Ilọrin, salaye pe ile iwe ni oun n lọ nigba ti igi naa sadede ya le awọn lori.
O ni ọkọ ti oun fẹ wọ ni oun n duro de labẹ igi ọhun koto di pe igi ja lu oun lẹyin ọrun.
Fatimsh ni ohun dupẹ lọwọ Ọlọrun nitoripe ẹmi ohun ko lọ sii, alaafia si ti n pada diẹ diẹ si agọ ara oun.
Mama rẹ to duro tii, Jamiu Salimata naa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ohun ko foju sukun ọmọ.
O ni lotitọ ni itọju ko duro lori ọmọ ohun sugbọn awon ko tii mọ ẹni ti yoo gbe owo itọju naa boya oun tabi ijọba.
Nigba ti BBC Yoruba kan si agbenusọ Ọlọpaa fun ipinlẹ Kwara, SP Okasanmi Ajayi lori iṣẹlẹ naa, o ni "otitọ ni ọrọ naa, eeyan meje ni gbogbo awọn to se kongẹ ibi naa, meji ku, marun si n gba itọju lọwọ ni ile iwosan.















