Ọmọ bíbí ọgá ọlọ́pàá tó yinbọn lù ọlọ́pàá méjì na pápá bora, ìwádìí bérẹ̀ ní pẹrẹwu

Aworan afurasi Drake Jr

Oríṣun àwòrán, LA VERGNE POLICE DEPARTMENT

O fẹ jọ bi sinima ṣugbọn iṣẹlẹ to waye la mu tọ yin wá.

Wọn ti da awọn agbofinro sita lati ṣe awari ọmọ ọga ọlọpaa kan lẹyin to yinbọn mọ awọn ọlọpaa meji kan ni Tennessee lorileede Amẹrika.

Ọmọ ọga ọlọpaa Nashville,ọga John Drake ti orukọ rẹ n jẹ John Drake Jr ni atẹjade kan ti àwọn ọlọpaa fi sita sọ pe k'awọn eeyan ṣọra fun tori pe o dira pẹlu nkan ija oloro.

Jakejado ipinlẹ Nashville ni wọn ti da agbofinro sita lati ṣawari rẹ lori ẹsun onigun meji pe o gbero lati gba ẹmi eeyan laibikita.

Afurasi ẹni ọdun mejidinlogoji yi ni wọn tí f'orukọ rẹ sori Asunwọn ọdaran to le julọ ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ FBI.

Owo moriwu wa fun ẹni ba tawa lolobo nipa afurasi yi - ọlọpaa

Aworan awọn ọlọpaa meji ti ibọn ba

Oríṣun àwòrán, LA VERGNE POLICE DEPARTMENT

Awọn agbofinro ko mu ọrọ arakunrin yi pẹlu ọwọ yẹpẹrẹ.

Wọn kede owo moriwu ẹgbẹrun meji aabọ dọla fún ẹnikẹni to ba ni iroyin nípa bi wọn ṣe lè rí arakunrin yi mu.

Ohun taa gbo pe o ṣẹlẹ ni pe arakunrin John Drake Jr yinbọn lu awọn ọlọpaa meji niluu La Vergne, Tennessee.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ilu taa n wi yi to jina ni ìwọn ogun mẹeli si guusu iwọ oorun Nashville lo ti yinbọn lu ọlọpaa ni ọjọ Abamẹta

Awọn ọlọpaa yi ,Ashley Boleyjack ati Gregory Kern - n ṣe iwadii ìṣẹlẹ kan to niiṣe pẹlu ọkọ tí wọn ji niwaju ile itaja kan.

Awọn mejeeji yi ko ti lo to ọdun mẹta lẹnu iṣẹ ọlọpaa.

Nigba ti wọn jijọ n wọ ara wọn pẹlu afurasi yi lo yinbọn fún àwọn mejeeji.

O jẹ iyalẹnu fun baba reẹ ọga agba ọlọpaa Drake lati mọ pe ọmọ bibi inu rẹ jẹ afurasi ninu iru ìṣẹlẹ iyinbọn bayii.

Bẹẹ lọ fi ọrọ sita ninu atẹjade kan to buwọlu.

O fi kun pe ọrọ ẹẹkọọkan lo waye laarin ohun ati afurasi yí lati igba to ti yan oju ọna ipanle to sì di ọdaran ti ile ẹjọ ti da'jọ fun.

Ọkan ninu awọn ọlọpaa yi la gbọ pe ọta ibọn bá ní ejika ti ibọn sí ba Ikeji ni apa ati aboonu.

Awọn dokita ni ki arabinrin Boleyjack maa lọ sile lẹyin to gba itọju ti a sí gbọ pe arakunrin Kern, ti ará rẹ ti n gba itọju yoo si wa ni ile iwosan fun igba diẹ na.

Ẹwẹ, olori ilu taa mọ si Mayor Freddie O'Connell sọ ninu atẹjade pe "Gbogbo ọkan mi wa lọdọ ọga ọlọpaa Drake ati idile rẹ to fi mọ awọn ọlọpaa meji to yinbọn lu.Mo mọ pe tohun ti igbiyanju wa gẹgẹ bi obi to fi mọ igba ewe wọn,a ko le wa tori rẹ da arawa lẹbi ti mọlẹbi wa kankan ba loun yoo ya bo ṣe wu u"