Erin tí inú rẹ̀ máa ń bàjẹ́ jùlọ jáde láyé

Mali

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Erin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mali tí àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹranko kan máa ń pè ní “erin tí inú rẹ̀ bàjẹ́ jùlọ láyé” ti jáde láyé.

Ilé àwọn ẹranko ní Philippine ni Mali gbé gbogbo ayé rẹ̀ ní òun nìkan.

Níṣe ni àwọn ènìyàn ti ń kọrin arò lẹ́yìn Mali, tó jẹ́ pé ó máa ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn lọ sí ibùgbé àwọn ẹranko Manila Zoo fún bí ogójì ọdún.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹarnko ló máa ń kọminú lórí bí erin náà ṣe jẹ́ òun nìkan nínú ibùgbé àwọn ẹranko ọ̀hún.

Ọ̀kan lára àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹranko náà ni Sir Paul McCartney, tó ní kí ìjọba Philippine gbé Mali kúrò níbi tó wà lọ sí ọgba táwọn erin mìíràn wà.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni adarí Manila, Honey Lacuna kéde ikú Mali nínú fídíò kan tó fi sórí Facebook, tó sì ní lára nǹkan tó máa ń dùn mọ́ òun jùlọ nígbà tí òun wà ní kékeré ni tí òun bá fẹ́ lọ wo Mali ní ibùgbé àwọn ẹranko.

Ní ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn ni erin náà ń fi imú rẹ̀ gbo ògìrì, èyí tó ṣàfihàn pé ó wà nínú ìnira gẹ́gẹ́ bí dókítà tó ń ṣètọ́jú àwọn ẹranko náà, Heinrich Patrick Pena-Domingo ṣe sọ.

Ó ṣàlàyé pé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ló sùn sílẹ̀ tó sì ń mí mímí akọ tó sì padà kú lọ́sàn-án ọjọ́ náà pẹ̀lú gbogbo oògun tí àwọn fún-un.

Àyẹ̀wò òkú rẹ̀ ṣàfihàn pé ó ní àìsàn jẹjẹrẹ ni àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ kan.

Mali, tí àpèjà orúkọ rẹ̀ jẹ́, Vishwa Ma’ali ni ìjọba Sri Lanka fi tọọrẹ fún aya ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí fún orílẹ̀ èdè Philippine, Imelda Marcos lọ́dún 1981 nígbà tó wà ní oṣù mọ́kànlá.

Nígbà náà, erin mìíràn, Shiva wà nínú ọgbà ẹranko Manila, tó sì ti wà níbẹ̀ láti ọdún 1977 kó tó kú lọ́dún 1990. Láti ìgbà náà sì ni Mali ti dá wà.

Ní gbogbo àsìkò tí àwọn ènìyàn wà ní ìgbélé lásìkò tí àìsàn Covid-19 ń jà ràìnràìn, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ló máa ń lọ wo Mali nínú ọgbà tó wà.

Mali àtàwọn ènìyàn tó wá wò ó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹranko ní ipò tí ọgbà àwọn ẹranko Manila wà kò dára tó àti pé wọn ò le pèsè ìtọ́jú tó yẹ fún Mali. Àmọ́ àwọn aláṣẹ ọgbà náà ní ibi tí Mali wà yìí gan ló yẹ ẹ́ nítorí kò máa gbé inú ijù láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀.

Nínú lẹ́tà kan tí Sir Paul kọ ránṣẹ́ sí ààrẹ Benigno Aquino nígbà tó wà nípò ní ìgbèkùn tí Mali wà ń ba òun lọ́kàn jẹ́.

Ó ní kí wọ́n gbé Mali lọ sí ọgbà àwọn erin tó wà ní Thiland lẹ́yẹ ò ṣọkà.

Bákan náà Morrisey náà kọ̀wé sí ààrẹ láti pé kí wọ́n gbé Mali k;urò nínú ọgbà Manila àmọ́ àwọn aláṣẹ Philippine kò gbé Mali kúrò.

Àwọn ènìyàn ṣèdárò Mali

“Ọ̀kan lára àwọn erin tí inú rẹ̀ ń bàjẹ́ ní àgbàyé ti papòdà,” àwọn ènìyàn People for the Ethical Treatment of Animal (Peta) ní kí Mali ó sùn ire.

Lórí ẹ̀rọ ayélujára X, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ní Philippine ní àwọn ṣe àbẹ̀wò sí Mali nígbà tí àwọn ṣe ìrìnàjò afẹ́ lọ sí ọgbà Manila tí wọ́n sì bu ẹnu àtẹ́ lu bí ó ṣe jẹ́ pé òun nìkan ló dá wà títí tó fi jáde láyé.

Ẹnìkan ní nígbà tí òun lọ sí Manila ní ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn, Mali kàn ń dárìn káàkiri ọgbà náà, tó sì hàn pé inú rẹ̀ kò dùn.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀rìyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́rú, adarí Manila ní òun máa bẹ ìjọba Sri Lanka fún àwọn ni erin mìíràn.

Ó ní ẹni tó ń tọ́jú Mali kàn ń sunkún láti ìgbà tí ẹranko náà ti dákẹ́ ni àti pé àwọn kò fìgbà kankan rò ó rí láti gbé Mali lọ sí ọgbà táwọn erin ẹgbẹ́ rẹ̀ wà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mali kò ní erin mìíràn tó lè bá ṣeré àmọ́ àwọn kò fi ìgbà kankan já lọ́dọ̀ rẹ̀.