Ìjọba àpapọ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó oṣù tuntun ní oṣù kẹrin ọdún 2024- Minisita

Aworan Idris Mohammed

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti jẹ ko di mimọ pe sisan owo oṣu tuntun fun awọn oṣisẹ ijọba yoo gbera sọ ni Ọjọ kinni oṣu kẹrin ọdun 2024.

Minisita fun eto iroyin, Idris Mohammed lo kede ọrọ ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle. The Punch niluu Abuja, o ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn ti awọn osisẹ n gba lọwọ yii yoo dopin ni ipari oṣu kẹta ọdun 2024.

Muhammad ni ijọba ti pese owo to le ni trilọnu mẹrinlelogun fun sisan owo oṣu awọn osisẹ ijọba lọdun 2024, 2025 ati ọdun 2026.

Lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu yọ owo iranwọ ori epo bentirool lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023, ijọba apapọ gba lati ma san owo toto ẹgbẹrun marundinlogogi fun awọn osisẹ lati mu aye dẹrun lẹyin ti ijọba yọ owo iranwọ epo bentirool.

“O ti di dan dandan pe ki owo oṣu tuntun bẹrẹ ninu oṣu kẹrin ọdun 2024. Idi ree ti a fi pese awọn ohun iranwọ lati mu aye rọrun ko to di pe abẹrẹ si ni san owo oṣu tuntun.

“Ninu ifọrowerọ wa pẹlu ẹgbẹ osisẹ Labour, a ni sisan owo oṣu yii ki se nnkan ti ẹnikan le da ṣe. Igbimọ gbọdọ wa ti ẹgbẹ osisẹ naa yoo si wa ninu igbimọ naa ti yoo sisẹ lori owo oṣu tuntun naa.

“A ti n ṣe igbakalẹ igbimọ naa bayii, ti a si n ba ẹgbẹ osisẹ sọrọ nipa rẹ. To ba ma fi di asiko ti owo oṣu ti wa gba lọwọ yoo fi pari ninu oṣu kẹta ọdun 2024, sisan owo oṣu yoo bẹrẹ ninu oṣu kẹrin ọdun 2024.

“Bakan naa a rọ awọn ijọba ipinlẹ ati ileeṣẹ adani lati tẹle ilana owo oṣu tuntun naa,”

Minisita Idris Malagi ti fi ọkan awọn ọmọ Naijiria balẹ pe aba eto isuna ọdun 2024 to le ni trilọnu mẹtadinlọgbọn yoo mu igbe aye awọn ọmọ Naijiria pada si daada ti ile igbimọ aṣofin ba buwọlu..