Nyesom Wike kò ní kúrò ní PDP, ó dá mi lójú – Saraki fèsì

Bukola Saraki ati Wike

Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin ni Naijiria tẹlẹ, Bukola Saraki ti ni o da oun loju pe gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ko ni fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lasiko yii.

Saraki sọ bẹẹ lẹyin iroyin to ja ranyin pe gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ati gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi lọ si olu ilu ipinlẹ Rivers, Port Harcourt lati lọ ṣe ipade pẹlu rẹ.

Iroyin ọhun ni wọn n gbiyanju lati parọwa si Wike lati fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ wa si APC.

Eyi ko ṣẹyin bi Wike ṣe fi apa janu lẹyin to kuna ninu idibo sipo aarẹ labẹle ni ẹgbẹ oṣelu PDP, eleyii to gbe abubakar Atiku wọle gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP.

Bakan naa ni Wike binu pẹlu yiyan gomina ipinlẹ Delta gẹgẹ bi igbakeji oludije si ipo aarẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Saraki lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni Ilorin ni ofo ni abẹwo awọn gomina lati ẹgbẹ oṣelu APC nitori PDP ko ni gba wọn laaye pe ki Wike kuro ni ẹgbẹ oṣelu naa.

‘’Gomina Wike ṣe pataki si ẹgbẹ oselu wa, ti mo si ni igbẹkẹle ninu rẹ pe gbogbo idojuk…ọ ẹgbẹ ni yoo ni iyanju laipẹ.’’

‘’O yemi pe Wike n binu, to si yẹ lati binu amọ a ko ni gba ki ogiri to lanu naa fẹ si’’

‘’Laipẹ gbogbo wa yoo joko papọ lati jiroro ati wa ọna abayọ si iṣoro ti a n koju ninu ẹbi wa ni ẹgbẹ oṣelu PDP.’’

Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu awọn gomina APC naa pe wọn ri ogiri to lanu, ti wọn fẹ rapala wọnu rẹ amọ ẹgbẹ oṣelu naa ko ni gba wọn laaye nitori ofo ni igbesẹ wọn.