Àwọn agbésùmọ̀mí tú èèyàn méje míì sílẹ̀ lára àwọn tí wọ́n jí gbé lójú ọ̀nà Abuja-Kaduna
Kaduna Train Attack: Àwọn agbésùmọ̀mí tú èèyàn méje míì sílẹ̀ lára àwọn tí wọ́n jí gbé lójú ọ̀nà Abuja-Kaduna

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn agbesumọmi to ji awọn arinrinajo gbe loju ọna oju irin Abuja-Kaduna gbe ti tu awọn meje mii silẹ lara awọn eeyan ti wọn ji gbe lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2022 yii.
Wọn tu awọn eeyan naa silẹ lẹyin ọgọrun ọjọ ti wọn ti wa ni igbekun awọn agbesumọmi ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ko tii fidi iroyin naa mulẹ, amọ ọkan lara awọn to n jiroro laarin ijọba Naijiria atawọn agbesumọmi naa, to tun ṣiṣẹ pẹlu olukọ ẹsin Musulumi, Sheikh Ahmad Gumi, Tukur Mamu sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle Channels pe wọn tu awọn eeyan naa silẹ lẹyin ifọrọwerọ pẹlu awọn ajinigbe ọhun.
Ṣugbọn ko sọ boya awọn agbesumọmi naa gba owo itusilkẹ kankan.
Lara awọn eeyan ti wọn tu silẹ gẹgẹ bii nnkan ti Mamu sọ ni, ọmọ alaga ẹgbẹ awọn agbagba iha Ariwa, Ọjọgbọn Ango Abdullahi, iyẹn Sadiq Abdullahi, Bosede Olurotimi, Abubakar Zubairu ati Alhassan Sule.
Awọn eeyan mii ti wọn tun tu silẹ ni Muhammad Daiyabu Paki, Aliyu Usman, ati ọmọ ilẹ okeere kan ṣoṣo to wa laarin wọn to wa lati Pakistan, Muhammad Abuzar Afzal.
Mamu ni wọn ti fa awọ eeyan meje naa le ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria lọwọ, wọn si ti tẹkọ leti lọ si Kaduna.
Wọn gba itusilẹ lẹyin ijiroro pẹlu awọn ajinigbe
Nigba to n sọrọ lori ipa ti ijiroro le ni lori eto abo to dẹnukọlẹ ni Naijiria, Mamu ni oun funra oun loun ṣiṣẹ lati tu awọn eeyan naa silẹ, pẹlu atilẹyin Sheikh Gumi.
O ni “Idi ree ti mo ṣe maa n sọ pe ijọba lagbara lati fopin si ijiya awọn eeyan wọnyii laarin ọjọ kan ṣoṣo.”
“Eeyan kan ṣoṣo leleyi to fi ẹmi rẹ sinu ewu, kii ṣe awọn ologun ni ọna abayọ si iṣoro eto abo Naijiria, ti ẹ ba ba awọn eeyan wọnyii sọrọ, wọn maa gbọ.”
“Mo ni ẹri to dantọ lọwọ pe awọn agbesumọmi yii yoo gbọ ti a bá ba wọn sọrọ, a ri awọn eeyan wọnyii tu silẹ nitori pe a ba awọn agbesumọmi naa sọrọ.”












