Ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò dáwọ́ dúró ní ìpínlẹ̀ Oyo

Lati ẹka ileeṣẹ ajọ eleto idibo INEC, to n bẹ ni ijọba ibilẹ Ibadan South West nipinlẹ Ọyọ. Ijọba ti dawọ iforukọsilẹ fun kaadi idibo duro gẹgẹ bi wọn ṣe kede rẹ saaju asiko yii.
Eyii lo si ṣe okunfa bi ọfisi ajọ naa ṣe da paroparo, nibi ti o jẹ pe ẹsẹ kii gba ero tẹlẹri.
Awọn eeyan to n wa lati gba kaadi idibo lẹyin iforukọsilẹ nikan lo n yọju sibẹ lọkọọkan-ejeeji bayii.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ naa ti o ba wa sọrọ fi idi rẹ mulẹ wi pe bi nnkan ṣe ri jakejada ipinlẹ Ọyọ niyii.








