Ọ̀kadà gígùn di èèwọ̀ ní ìpínlẹ̀ Katsina

Oríṣun àwòrán, other
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Katsina ti fi idi rẹ mulẹ pe ko gbọdọ si lilọ bibọ alupupu ọkada mọ kaakiri ipinlẹ Katsina.
Igbesẹ yii n waye lẹyin lẹyin oṣu mẹrin ti ijọba ipinlẹ naa ti kede pe ki wọn gbẹsẹ kuro lori ofin fun igba diẹ lati lee mu ki o rọrun fun awọn eeyan lati ṣe awẹ Ramadan nigba naa.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, SP Gambo Isah ileeṣẹ ọlọpaa ni agbekalẹ ofin to de lilo ọkada nipinlẹ naa pada si iṣẹ lẹyin ti wọn ṣakiyesi bi awọn agbebọn ati agbesunmọmi ṣe n lo o lati ṣe ikọlu wọn nibẹ.
“Nibayii, ofin to de gigun ọkada yoo wa nikalẹ lati dena gigun ọkada laarin agogo mẹwaa alẹ si mẹfa owurọ lojoojumọ.”
Amọṣa atẹjade naa fi kun un pe ofin naa yoo dena gigun ọkada laarin agogo mẹfa irọlẹ si agogo mẹfa aarọ lawọn agbegbe ti ikọlu awọn agbebọn naa ti n waye lemọlemọ.
Ipinlẹ Katsina wa lara awọn ipinlẹ ti ikọlu awọn agbebọn ati agbesunmọmi ti burẹkẹ julọ lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria nibi ti ikọlu awọn agbebọn ti gogo julọ.
Titi kan awọn ipinlẹ bii Kaduna ati Zamfara to yii ipinlẹ Katsina ka ni gbọnmọgbọnmọ ikọlu wọnyii ti n waye.








