Wo bí ìwádìí ọlọ́pàá ṣé ṣàwárí arábìnrin ìbátan ọmọ òrukàn méjì tí wọ́n bá òkú wọn nínú àpótí aṣọ

Aworan afihan ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, AFP

Ileeṣẹ ọlọpaa lorileede New Zealand ti kede pe awọn ti fẹsun kan arabinrin kan ni South Korea lori iku awọn ọmọde meji kan ti wọn ba oku wọn ninu apoti aṣọ loṣu to kọja.

Iṣẹlẹ yi to ya ọpọ eeyan lẹnu la gbọ pe o ṣẹlẹ nigba ti awọn ajoji kan ba oku awọn ọmọ mejeeji yi ninu apoti aṣọ ti wọn ra ni aaye ikẹrupamọsi kan ni Auckland.

O to ọdun meloo kan tawọn oku yi ti wa ninu awọn apoti taa n wi yi.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọjọ ori awọn ọmọ naa wa laarin ọdun marun un si mẹwaa.

Ṣaaju lawọn agbofinro ti kọwe sawọn alaṣẹ ni South Korea pe ki wọn fawọn laaye la ti gbe obinrin naa pada wa labẹ ofin wa wi tẹnu rẹ.

Ọlọpaa ni niṣe lawọn n ṣiṣẹ papọ pẹlu ọlọpaa South Korea fọsẹ mẹta lẹyin ti wọn s loṣu to kọja pe awọn nigbagbọ pe South Korea lo ṣi wa.

Wọn lawọn tọ ipaṣẹ rẹ lẹyin ti wọn ribi mọ orukọ ati ẹni tawọn ọmọde naa jẹ. Wọn ko darukọ awọn ọmọ naa lati le daṣọ aṣiri bo wọn.

''Lati le ri afurasi gbe wa lati ilẹ okere laarin akoko diẹ yi, o gbọdọ ṣe pe o lọwọ iranwọ awọn alaṣẹ Korea ninu ati ajọṣepọ awọn ọlọpaa Interpol ti New Zealand''

Ọrọ ti Insipẹktọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ Tofilau Fa'amanuia Vaaelua sọ ree.

O ni lowurọ Ọjọbọ lawọn ọlọpaa South Korea mu arabinrin naa ati pe awọn ọlọpaa New Zealand yoo kọwe ki ile ẹjọ ma jẹko gba oniduro beeli ṣaaju ki wọn to da pada.

O fi kun pe awọn dupẹ lọwọ awọn araalu to ṣe atilẹyin olowo iyebiye fawọn ọlọpaa nidi iwadii wọn.

Àkọlé fídíò, Ojọgbọn Adeboye Odunayo Clement: Ìdí ti UniOsun kò se darapọ̀ mọ́ ìyansẹ́lódí ASUU

Bawo l'obirin naa ṣe jẹ sawọn ọmọ yii?

Awọn ileeṣẹ iroyin labẹle sọ pe o dabi ẹni pe ibatan awọn ọmọ naa ni obinrin yi jẹ.

Wọn ni mọlbi yi ti gbe ni Auckland fun ọdun diẹ ati pe baba awọn ọmọ yi ti ku ṣaaju kawọn naa to kagbako iku.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe mọlẹbi to ri oku awọn ọmọ yi lọ ra ẹru tirela kan nibi ti wọn kẹrupamọ si ko to di pe wọn ba oku awọn ọmọ naa ninu apoti ti wọn ra.

Àkọlé fídíò, Damilola Olofingboyegun ọmọ olóògbé:Gbenga Olofingboyegun kò sí aàbò mọ́, ìrànlọ́wọ́ ni à

Ọlọpaa ni mọlẹbi yi to ra ọja ni ibẹrẹ oṣu kẹjọ ko mọ nkankan iku awọn ọmọde yi.

Wọn fi kun pe niṣe ni iṣẹlẹ yi ko idaamu ba wọn lyin ti wọn ri oku awọn ọmọ naa ninu apoti aṣọ.