"Ife ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì wọn, mo tàn-án wọ ṣọ́ọ̀ṣì wa, mo fipá ba lòpọ̀, fun lọ́rùn pa"

Afurasi Apaniyan

Oríṣun àwòrán, Oyo state Police Command

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ti ṣafihan afurasi ẹni ogun ọdun kan, to si ti sọ bi oun ṣe fipa ba ọmọdebinrin kan lopọ, ko to pa a sinu ile ijọsin kan ni Ibadan.

Adugbo Olodo ni arakunrin Kolade Tosin ṣalaye fawọn agbofinro pe oun pa arabinrin naa si, tori pe o fun oun ni ayederu passwọọdi foonu to wa lọwọ rẹ.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ladugbo Eleyele ni Ibadan, o ni ọbẹ loun lo lati fi dẹru ba arabinrin naa, ki oun to hu iwa aburu yi.

"Mo tan Ifeoluwa pe ko ba mi ko aga ile ijọsin"

Afurasi yii ṣalaye fawọn akọroyin lasiko afihan rẹ naa, nipa ọna to gba hu iwa aburu yi.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ''lọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹsan 2022 ni mo lọ si ile ni nkan bi ago kan ọsan, lẹyin ti mo parọ fun ọga mi pe mo fẹ lọ ṣe igá.

Ọga mii si ni ki n ma pẹ pada''

O tẹsiwaju pe ''Mo mu kọkọrọ ile ijọsin lẹyin ti mo de ile tori maami ni wọn maa n tun ile ijọsin ṣe.''

Nigba ti mo de ile ijọsin, mo ko gbogbo aga si ẹgbẹ kan mo si n ṣọ igba ti Ifeoluwa yoo kọja.

Bo ṣe kọja ni mo sọ fun pe ko ran mi lọwọ lati to awọn aga, ki o to maa lọ si ile ijọsin tiẹ.''

Lẹyin igba naa ni afurasi yii sọ pe oun fa ọbẹ yọ si Ifeoluwa, "ti mo si sọ fun pe ko ma ṣe pariwo sita''

''Mo fẹ gba foonu ọwọ rẹ ṣugbọn o bẹrẹ si ni lọ ọbẹ mọ mi lọwọ.

Nibẹ lo ti ṣubu to si fi ori gbalẹ nigba to fẹ́ salọ.''

"Mo fi ipa ba lopọ nigba ti ko le gbera mọ"

Kolade ṣalaye siwaju fawọn akọroyin bo ti ṣe fipa ba Ifeoluwa lopọ nigba ti o ri pe ko lagbara lati salọ.

''Nigba ti ko lagbara mọ, mo fi ipa ba lopọ. Mo gba foonu rẹ mo si sọ fun pe ko fun mi ni pasiwọọdu rẹ.

Ayederu pasiwọdu lo gbe le mi lọwọ. Nigba ti mo ri bẹẹ ni mo fi wa fun lọrun pa''

Kọmiṣana ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo, Adebowale Williams sọ pe awọn agbofinro ni agọ ọlọpaa Iyana-Offa ni wọn fi to leti pe Ifeoluwa ti dawati.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ẹni ọdun mẹtadinlogun naa kuro ni ile ijọsin ni nkan bi ago mẹrin, ko si pada dele.

Kọmiṣana sọ pe iwadii ibẹrẹ, awọn fihan pe wọn ri oku arabinrin yii lẹgbẹ ile ẹkọ bibeeli lagbegbe Olodo.

O ni ẹjẹ wa loju ara rẹ ti apẹrẹ si wa wipe o ja fita ki o to pada gbẹmi mi.

Adebowale Williams fi kun pe wọn ti gbe ọrọ naa lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa, nibi ti iwadii yoo ti maa tẹsiwaju.