O parí! Joe Biden ní Covid-19 dohun ìgbàgbé l‘Amẹ́ríkà ṣùgbọ́n...

Aworan Aarẹ Amẹrika Joe Biden

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Amẹrika Joe Biden ti kede pe ajakalẹ Covid-19 ti dopin nilẹ́ naa tohun ti bi iye awọn ti aarun naa mu ẹmi wọn lọ ṣe n pọ si.

''A ṣi n ṣiṣẹ takun lori rẹ ṣugbọn ajakalẹ yi ti dopin''

Esi ti aarẹ Biden fọ re lasiko to n kopa lori ifọrọwanilẹnuwo kan lori ẹrọ amohunmaworan ni Amẹrika.

Akọsilẹ fihan pe o kere tan irinwo ọmọ Amẹrika ni o n ba aarun yi lọ lojojumọ.

Ọga agba ajọ ilera lagbaye WHO sọ lopin ọsẹ to kọja pe opin ti n de ba aarun yi.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti aarẹ Biden ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin CBS lori eto 60 Minutes eyi ti wọn gbe sori afẹfẹ lọjọ Aiku,Biden ni nkan n gberu si pẹlu kikoju aarun yi ati pe ọpọ iṣẹ lati dẹkun rẹ lawọn n ṣe.

Nibi ti wọn ti n ṣe ifọrọwanilẹnuwo yi jẹ ibudo eto ipatẹ ọkọ Detroit Auto Show.

Niṣe ni aarẹ Biden naka si awọn to n wo eto naa to si sọ pe''bi ẹ ba ṣakiyesi, e o ri pe ko si ẹni to lo ibomu ninu awọn to duro yi''

''Ara gbogbo wọn da ṣaka...Mo lero pe nkan ti n yi pada''

Ohun ti ijọba sọ yatọ si ti aarẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn oṣiṣẹ ijọba sọ fawọn akọroyin ilẹ Amẹrika lọjọ Aje pe ọrọ aarẹ ko tunmọ si pe ilana ijọba ti wa yatọ bayii lori aarun naa ati pe awọn ko lero lati gbẹsẹ kuro lori ofin pajawiri to de aarun Covid-19 to wa lode.

Ni oṣu Kẹjọ awọn alaṣẹ fi ọjọ kun itẹsiwaju ofin pajawiri aarun Covid-19 to ti wa lode lati oṣu Kini ọdun 2020 titi di ọjọ Kẹtala oṣu Kẹwaa.

Titi di ba ṣe n sọrọ yi, o le ni miliọnu kan ọmọ Amẹrika ti Covid-19 ti mu ẹmi wọn lọ.

Iroyin to tẹwa lọwọ lati fasiti John Hopkins fi han pe laarin ọjọ meje o kere tan eeyan to n padanu ẹmi wọn lọwọ Covid-19 ti le ni irinwo ti awọn ti Covid-19 mu lọ lọsẹ to kọja nikan si ju ẹgbẹrun mẹta lọ.

Ni oṣu Kini ọdun 2021 ni afiwe,iye awọn ti aarun yi pa lọsẹ kan ṣoṣo nigba naa lọhun le ni ẹgbẹrun mẹtalelogun.

Nkan bi ida marundinlaadọrin ninu ida ọgọrun eeyan Amẹrika lo ti gba abẹrẹ perepere.

Awọn abẹrẹ ajẹsara ijọba apapọ kan jẹ dandan ni gbigba titi di asiko yi to fi mọ eleyi tawọn oṣiṣẹ ilera n gba ati tawọn ajoji mii to ba n ba baalu wọ orileede wọn.

Kii ṣe gbogbo eeyan lo gba ti ọrọ aarẹ Biden

Awọn eekan ninu ẹgbẹ alatako Republicans kan ti bẹnu atẹ lu ọrọ aarẹ Biden.

Ninu wọn la ti ri akọwe ijọba apapọ tẹlẹ Mike Pompeo to kọ soju opo Tweeter pe ''Biden ni ajakalẹ ti tan to si n le awọn ọmọ ogun ti ara wọn da ṣaka kuro lori aigba abẹrẹ ajẹsara to mu ni dandan''

Awọn oṣiṣẹ ilera ti fi ero ọkan ti wọn naa han pe awọn ko le ti bawọn dunnu lori ọrọ yi ti wọn si n gba awọn eeyan niyanju lati tẹsiwaju maa gba abẹrẹ ajẹsara.

Lọjọ Aje, onimọ ilera Anthony Fauci to jẹ olori ibudo iwadii nipa aisan ati kokoro aifojuri ni lootọ ni nkan ti yatọ si ti tẹlẹ amọ ninu ọrọ rẹ o tun sọ pe iye awọn to n ku lojumọ ga kọja nkan ti eeyan le farada.

''A ko ti de ibi to wuwa lati de ti a ba fẹ́ maa gbe igbe aye pẹlu ajakalẹ yi.''

Bakan naa lo kilọ pe o ṣeeṣe ki awọn ẹda aarun yi miran tun pada yọju ni paapa bi oṣu otutu Winter ṣe n bọ niwaju.