Iléẹjọ́ wọ̀gile ẹ̀sùn ípànìyàn fún ọkùnrin kan lẹ́yìn ogún ọdún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, EPA
Adajọ Melissa Phinna ti da ọmọ orilẹede Amẹrika kan lare pe ko jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan lẹyin to ti lo ogun ọdun ni ọgba ẹwọn.
Adnan Syed, ẹni to wa lati Baltimore, wa ni ọmọ ọdun mọkandinlogun nigba ti ileẹjọ ran lọ si ẹwọn gbere.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o ṣekupa ọrẹbinrin rẹ, Hae Min Lee lọdun 1999.
Awọn olupẹjọ, lọsẹ to kọja sọ fun ileẹjọ pe ko ma gba lati wọgile ipẹjọ kotẹmilọrun naa.
Syed yoo ni anfani lati wa ni ile rẹ sugbọn ko ni anfani lati bọ sita.
Ni bayi, Adnan Syed, ẹni ọdun mọkanlelogoji, ni wọn ti gbe ẹjọ naa kuro ni ileẹjọ lẹyin to ti lo ọdun mẹtalelogun ni atimọle.
Adajọ Melissa Phinna ni oun wọgile ẹjọ naa nitori pe ko dara lati fi iyajẹ eeyan ni ọna aitọ.
O fikun pe ijọba kuna lati gbe ẹri to peye kalẹ lori ẹsun ti wọn fi ọkunrin naa.
Phinna ni ipinnu ileẹjọ ko tumọ si pe ọwọ Syed mọ rara.
Adajọ Phinn wa ti pasẹ fun ipẹjọ miiran.
Ileẹjọ ni Syed jẹbi ẹsun ẹgbẹrun meji iṣekupani, ijinigbe, ole jija ati igbe ẹnipamọ ni ọna aitọ.
Awọn olupẹjọ ni awọn ko faramọ nitori pe Syed lo ṣekupa Lee, akẹgbẹ rẹ ni ile ẹkọ giga Woodlawn, pẹlu iranlọwọ ọrẹ rẹ, ti wọn jọ gbe oku pamọ sinu igbo
Kíló fàá tí alága Àjọ àwọn ọlọ́pàá, Musiliu Smith fi kọ̀wé fi ipò sílẹ́?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọga agba ọlọpaa tẹlẹri ni Naijiria, Musiliu Smith ti kọ iwe fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi alaga ajọ to n risi ọrọ awọn ọlọpaa ni Naijiria, Police Service Commission (PSC).
O ṣeeṣe ki ifipo silẹ rẹ niiṣe pẹlu aigbọra ẹniye to waye laarin ileeṣẹ ọlọpaa lati ajọ to n risi ọrọ ileeṣẹ ọlọpaa lori igbanisiṣẹ.
Alaga ajọ naa lo fi iwe ikọwe fi ipọ rẹ silẹ ranṣẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari ni ọsẹ to kọja, ti aarẹ si buwọlu lu u ni Ọjọ Iṣẹgun.
Agbẹnusọ fun ajọ naa, Austin Braimoh to fidi ọrọ naa mulẹ ni ọrọ eto ilera ọga agba ọlọpaa tẹlẹri naa lo jẹ ko kọwe fi ipo silẹ, to si fi ranṣẹ si aarẹ.
O fikun un pe aarẹ nikan lo ni aṣẹ lati yan alaga ajọ ọlọpaa amọ titi ti aarẹ yoo fi yan adajọ fẹyinti, Lara Ogunbiyi yoo fi wa ni ipo.
Tani o laṣẹ lati gbani si iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria?
Awuyewuye n waye laarin ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria ati Ajọ to n risi ọrọ ọlọpaa ni Naijiria lori ẹka to lagbara lati gba eniyan si iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.
Laipẹ yii ni Ajọ ọlọpaa PSC fi ikede sita pe awon fe gba awọn eeyan si ise constable ti won si ro eni to ba ni ife si ise naa lati lo si oju opo won.
Amo ileese olopaa ninu oro ti won fi lede ro awon araalu lati fi owo osi da ikede naa nu.
Won fikun un pe nitori awon nikan lo lase lati kede igbanisise ati gbigba awon eniyan si ise.
Odun 2018 ni aare Buhari yan Smith si ipo alaga Ajo Police Service Commission lati maa bojuto.












