Evans rí ẹ̀wọ̀n ọdún mọ́kànlélógún hé fún ẹ̀sùn ìjínigbé

Ile ẹjọ giga nipinlẹ Eko ti ran ajinigbe, Chukwudumeme Onwuamadike, ti ọpọ mọ si Evans lọ si ẹwọn ọdun mọkanlelogun.
Bakan naa ni amugbalẹgbe rẹ, Victor Aduba yoo se ẹwọn iye ọdun kan naa pẹlu Evans fun bi wọn ṣe ji okunrin kan ti orukọ rẹ jẹ Sylvanus Hafia gbe pamọ.
Adajọ Oluwatoyin Taiwo lo gbe igbẹjọ naa kalẹ niluu Eko loni ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan an ọdun 2022.
Ọwọ tẹ awọn ajinigbe naa lọdun 2014 ni agbegbe Kara ni Amuwo Odofin niluu Eko lẹyin ti wọn ji Hafia gbe.
Awọn ajinigbe naa tun beere owo itusilẹ milọnu mẹji dọla, owo ilẹ okeere.
Awọn olujẹjọ mejeeji naa lo sọ fun ilẹẹjọ giga ipinlẹ Eko pe awọn ko jẹbi ẹsun mẹrin ti wọn fi kan wọn.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Taiwo ni igbẹjọ naa ni yoo jẹ ẹkọ fun awọn yooku to lọwọ ninu iwa ajinigbe ni Naijiria.
Idajọ wo lo waye tẹlẹ nipa Evans?
Saaju ni ọwọ sinkun ọlọpa ti tẹ Evans ati amugbalẹgbẹ rẹ fun ẹsun ijinigbe lọjọ Kẹwa osu Kẹfa ọdun 2017.
Lẹyin atotonu ikọ olupẹjọ ati olujẹjọ, ni Adajọ Hekeem Oshodi tileẹjọ giga ipinlẹ Eko ti sọ Evans ati amugbalẹgbẹ naa sẹwọn gbere.
Ọjọ kejilelogun osu Keji ọdun 2022 si ni idajọ naa waye, idi si ree ti Evans se pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa.
Nibayii, adajọ ti wa ni ki Evans ati amugbalẹgb rẹ lọ lo ọdun mọkanlelogun lọgba ẹwọn, dipo ẹwọn gbere ti ile ẹjọ akọkọ kọkọ da fun wn.
















