Ibadan NURTW: Kíni ó n ṣẹlẹ̀ ní Ibadan pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwakọ NURTW?

Oríṣun àwòrán, Others
Ki lo n ṣẹlẹ n'Ibadan pẹlu ọrọ ẹgbẹ awakọ NURTW?
L'Ọjọru ni iroyin kan gbode pe ẹgbẹ awakẹ ero, 'National Union of Road Transport Workers', NURTW ẹka ti ipinlẹ Ọyọ ṣe ifilọlẹ igbimọ tuntun ti yoo maa ṣe akoso ẹgbẹ naa.
Ninu igbiyanju lati ṣe atungbeyẹwo bi ẹgbẹ naa ṣe n ṣiṣẹ si n'ipinlẹ Ọyọ, ati fun awọn abajade ọtun, awọn alakoso ẹgbẹ naa lati olu ile iṣẹ wọn ti ṣe ifilọlẹ igbimọ ẹlẹni mejidinlogun ti yoo maa mojuto ẹgbẹ naa n'ipinlẹ Ọyọ.
- Lẹ́yìn ò rẹyìn ìjọba àpapọ̀ tú àwọn ọmọ ìkọ̀ IPOB mẹ́ta sílẹ̀
- Kíló kàn? Wo ọ̀pọ̀ èrò tó ti ń wá wo Òkú Obabìnrin Elizabeth II ní Gbọ̀ngan Westminster
- Èèyàn àádáta kàgbákò Ìjínigbé lọ́wọ́ agbébọn ní Katsina
- Wo ọ̀pọ́ àwòrán ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ti kópa nínú eré ìdárayá
- Ìjọba mi ti ṣiṣẹ́ dáadáa, mo ṣi gbìyànjú láì náání ìṣòro ètò aàbò- Buhari-
Kini o bi igbesẹ tuntun laarin ẹgbẹ NURTW yii?
Igbesẹ yii lo si n waye lẹyin ti wọn tu igbimọ to n dele fun awọn alamojuto ẹgbẹ naa ka labẹ akoso Arakunrin Kayode Agbeyangi.
Lasiko to n ṣe ifilọlẹ igbimọ tuntun naa l'Abuja, aarẹ ẹgbẹ naa, Alhaji Tajudeen Ibikunle Baruwa kesi awọn aṣoju igbimọ tuntun eleyii ti Alhaji Abideen Olajide(Ejiogbe) jẹ adari fun lati rii daju wi pe iṣọkan wa ninu ẹgbẹ naa, to fi mọ arọwa si awọn ọmọ ẹgbẹ to n fi apa janu.
Iyatọ wo ni awọn ikọ mejeeji mẹnuba?
Awọn nnkan mii ti aarẹ ẹgbẹ tọka si ni ibanisọrọ laarin ẹgbẹ naa ati awọn alaṣẹ ijọba pẹlu erongba lati riidaju wi pe ẹgbẹ NURTW pada sẹnu iṣẹ n'ipinlẹ Ọyọ ati lati dẹkun awọ ẹjọ to n lọ lọwọ nile ẹjọ.
Ọpọ eeyan lo ro wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ti wọgile aṣẹ ti o fi de ẹgbẹ naa lasiko ti iroyin ifilọlẹ awọn igbimọ tuntun jade sita, ṣugbọn ohun ti a le fi idi rẹ mulẹ ni wi pe igbiyanju lati pada sẹnu iṣẹ lo mu ki ẹgbẹ naa ṣe ifilọlẹ awọn alakoso tuntun.
Ninu oṣu karun un ọdun 2019 ni ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde fi ofin de ẹgbẹ awakọ ẹro NURTW lori ẹsun aṣemaṣe ati gbodonroṣọ to waye ninu ẹgbẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn igun meji lo kọju ija si ara wọn ninu ẹgbẹ naa nitori ipo adari ẹgbẹ.
Igun ikini tẹle alaga ẹgbẹ naa, Abideen Olajide, gẹgẹ bi igun ikeji ṣe to sẹyin alaga tẹlẹri, Mukaika Lamidi.
Ninu oṣu keji, ọdun 2020 ni Gomina Ṣeyi Makinde ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ tuntun ti yoo maa ṣe akoso igbokegbodo ọkọ jakejado ipinlẹ Ọyọ, iyẹn Park Management System, PMS, labẹ akoso Arakunrin Mukaila Lamidi ti ọpọ eeyan mọ si "Auxiliary".
Nigba ti yoo fi di oṣu kẹrin ọdun 2020 ni awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW bẹrẹ sini fi igbe ta wi pe airi iṣẹ ṣe ti mu ki ebi maa pa wọn, ti wọn si kesi ẹgbẹ apapọ awọn ọmọ ilẹ Ibadan, 'Central Council of Ibadan Indigenes', CCII ati awọn eekan mii lati ba wọn ra ọwọ ẹbẹ si Gomina ki o le wọgile ofin ti o fi de wọn, ṣugbọn eti ọgboin ni Makinde kọ si ẹbẹ naa.














