Katsina Kidnap: Ọlópàá Katsina bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí agbébọn tó jí èèyàn àádọta gbé, tó tún sẹkúpa ẹnìkan

Ọkunrin agbebọn

Oríṣun àwòrán, other

Iroyin to wa lati agbegbe ariwa Naijiria fi to wa leti pe awọn ajinigbe tun ti soro bi agbọn.

Ni abule Bakiyawa nipinlẹ Katsina awọn araalu sọ fun BBC pe aimọye awọn ọkunrin lo yabo abule awọn laarin oru lori ọkada.

Wọn ṣalaye pe niṣe ni wọn dabọn bolẹ ti wọn si pa eeyan kan ti awọn o kere tan, meje mii si farapa.

Lati ibẹ, wọn lawọn alaburu yi ji to eeyan aadọta gbe salọ ti awọn obinrin si wa ninu awọn ti wọn jigbe.

A tun gbọ pe awọn agbebọn wọnyi ji nkan ọsin ati ounjẹ awọn araalu gbe salọ.

Agbegbe ti iṣẹlẹ yi ti waye ko jina ju kilomita mẹwaa lọ si olu ilu ipinlẹ Katsina.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa kan sọ fun BBC pe awọn agbofinro doju ija kọ awọn agbebọn to dira gidi gaan.

Àkọlé fídíò, Soji Taiwo:Yekeen Ajileye ló gbé mi síta pẹ̀lú ìyá Gbónkán tí mo fi sọ pé olè ni ọkọ ajẹ́

Amọ igbiyanju wọn ko ribi di ijinigbe awọn eeyan lọwọ.Awọn alaṣẹ lawọn n gbe igbesẹ lati ribi doola awọn ti wọn jigbe.

Ipinlẹ Katsina ni ipinlẹ ti aarẹ Buhari ti wa.Iṣẹlẹ yi si n waye lasiko ti ọpọ n bẹnu atẹ lu bi aarẹ ko ṣe ribi koju ipenija aabo to gbale gba oko.

Awọn janduku ajinigbe ati agbebọn ti pọ kaakiri ti wọn a si maa beere owo idoola ki wọn to tu awọn eeyan silẹ.

Agbegbe iwọ oorun ariwa Naijiria ni awọn alaburu yi ti rinlẹ amọ ikọlu yi n waye lẹyin igba to dabi pe wọn sinmi diẹ.