Lẹyìn ọdún mẹ́fà,ọwọ́ tẹ àwọn adigunjalè tó n wọ wíìgì obìnrin jà awọ́n arìnrìnàjò lólè nínú reluwé

Ọkọ reluwee ayarabiasa to n gbe ero laarin Paris si Geneva ati Nice.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọwọ palaba awọn ikọ ogbori ọlọṣa to n de wiigi obinrin fi ja awọn eeyan lole ninu ọkọ reluwe ti segi ni ilẹ Faranse.

Gẹgẹ ba ṣe gbọ, wọn ti gba nkan ini awọn eeyan to le ni ọọdunrun lọna ẹgbẹrun Euro (€300,000) to ṣe deede mejildinlaadoje le diẹ miliọnu Naira(₦128,642,124.) ki wn to ri wọn mu.

Ọna ti wọn ro pe wọn fi n ja awọn eeyan lole ni pe wọn a maa ji ẹru awọn ti wọn ba joko sẹgbẹ wọn ninu reluwe ayarabiaṣa.

Ọkan ninu awọn agbewiri yi jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ti o si maa n wọ wiigi sori bi ti obinrin to ba fẹ ja awọn eeyan lole.

Arakunrin yi ati awọn meji mii ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ati ẹni ogoji ọdun kan ti jẹwọ pe awọn ti n ja awọn eeyan lole lati nkan bi ọdun mẹfa sẹyin.

Awọn ọlọpaa ni niṣe ni wọn n ko awọn ẹru ti wọn ji pamọ si inu ile kan ni Guusu ilu Marseille.

Ọna ti wọn fi n ja awọn eeyan lole ni pe wọn a maa ji nkan ini awọn eeyan to ba dide nasẹ nigba ti ọkọ reluwe ba duro sinmi fawọn arinrinajo.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Loṣu kẹrin ọdun ni eeyan kan kọkọ ta awọn ọlọpaa lolobo nigba ti wọn ji ẹṣọ ara ti owo rẹ to €50,000 ninu baagi ọwọ arinrinajo kan.

Oṣu mẹrin lyin igba naa ọlọpaa ṣawari ile kan ti wọn ko awọn ẹru ole pamọ si ni Marseille.

Ninu awọn nkan ti wọn ri nibẹ ni owo €130,000 ago ọwọ €70,000 ati awọn aṣọ,baagi, bata,kamẹra ati ẹṣọ ara.

Ọlọpaa lo ṣeeṣe ki wọn ti ja to eeyan ọgọrun lole awọn nkan ini wọn.

Igbiyanju ti bẹrẹ lati wa awọn to wọ ọkọ reluwee laarin Paris,Geneva ati Nice boya wọn le jẹ ri awọn to ni dukia wọnyi.

Bi ileẹjọ ba da wọn lẹbi, o ṣeeṣe ki awọn arakunrin yi lo to ọdun meje lẹwọn lori ẹsun ole jija.