"Màá kán apá àti ẹsẹ̀ mi, kí n le bọ́ lọ́wọ́ Putin tó ń fi tipá mú wa lọ sójú ogun"

Lẹ́yìn ìkéde Putin, ọ̀pọ̀ èèyàn n yà kúrò ní Russia

Ọkunrin ti ọlọpaa mu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọmọ orilẹede Russia ti bẹrẹ si ni sa kuro lorilẹede naa lẹyin ti ijọba kede afikun awọn ọmọ ogun lati lọ koju orilẹede Ukraine.

Ogunlọgọ awọn eeyan Russia si ti balẹ si awọn agbegbe igberiko lati igba ti Aarẹ Vladimir Putin ti se ikede naa.

Koda, ijọba yoo ṣe idanilẹkọ fun awọn eeyan toto ẹgbẹrun lọna ọọdunrun lati lọ koju orilẹede Ukraine.

Pupọ ninu awọn ọkunrin to wa ni ọjọ ori to le darapọ mọ awọn ologun, ni wọn ti bẹrẹ lati ma sa kuro ni agbegbe wọn, ki wn maa baa kopa ninu ogun naa.

Ọkunrin kan ti ko darukọ rẹ, sọ fun BBC pe kete bi Aarẹ Putin ti gbe ikede naa jade, ni oun ti mu iwe irinna oun.

O ni ti oun ko si idi ẹru kankan dani nitori ọjọ ori oun wa lara awọn ti wọn le ran lọ si oju ogun.

Awọn osojumikoro to wa nibi isẹlẹ naa ni ọpọlọpọ ọkọ ayọkẹlẹ lo ti wọ awọn igberiko, ti sukẹrẹ fakẹrẹ si gba gbogbo ojo opopona.

Fọnran kan safihan bi awọn awakọ ṣe n fi ọkọ silẹ nitori bi ọna ṣe di pa.

Orilẹede Georgia ni orilẹede kan to sunmọ ilẹ Russian, ti awọn eeyan si ti sa lọ sibẹ lai nilo iwe irinna.

Finland naa wa lara awọn orilẹede ti ọpọ wọn salọ sugbọn wọn nilo iwe irinna lati wọ orilẹede naa.

Aworan

Awọn orilẹede to mule ti Russia n fi owo kun owo tikẹẹti baalu

Awọn agbegbe yoku to tun mule ti Russia ni Istanbul, Belgrade tabi Dubia.

Awọn ilu wọnyi ni wọn ti fi owo kun owo tikẹẹti wọn ni kete ti Aarẹ Putin ṣe ikede naa.

Minisita to wa feto irina lorilẹede Germany, Nancy Faeser, ni orilẹede naa ti ṣetan lati tẹwọ gba awọn ọmọ Russia to ba sa wa si ilu wọn.

Sugbọn orilẹede Lithuania, Latvia, Estonia ati Czech Republic ni awọn ko ni fun awọn awọn ọmọ Russia ni anfani lati wọ ilu awọn.

Aworan

Mó má kán apá, ẹsẹ àti ṣé ohùn kònu láti má lé darapọ̀ mọ ikọ ológun

Ọkunrin kan ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, to jẹ akẹkọọ ati olukọ ni wọn ti pe lati wa darapọ mọ ikọ ologun naa.

Ọkunrin naa ti ko darukọ rẹ fun ileeṣẹ BBC, sọ pe ni kete ti Aarẹ Putin pari ikede ni awọn meji kan sabẹwo si oun.

O ni wọn si fun ni iwe kan lati tọwọ bọ gẹgẹ bi ọmọ ologun.

O ni oun ro pe awọn to ba ni iriri nipa ogun ni wọn maa ransẹ si lati wa ja ogun Ukraine sugbọn eyi ko ri bẹẹ.

Ikede naa lo ti fa ọpọlọpọ ifẹhonuhan ni olu ilu Russia, Moscow ati St Peterburg, ti wọn si ti mu eeyan to ju ẹgbẹrun kan lọ si ahamọ.

Iroyin ni pupọ lara awọn to wa ni ahamọ ni awọn to ti tọwọ bọwe lati lọ soju ile Russia.

Aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymyr Zelensky ti rọ awọn eeyan Russia lati maṣe gba lati darapọ mọ ikọ ologun lati koju Ukraine.

O ni pupọ awọn eeyan ti ba ogun naa lọ.

“Ẹ fẹ si? Rara? ẹ fẹhonuhan, ẹ salọ tabi ki ẹ farayin kalẹ fun awọn ologun Russia.”