Ilé asòfin Ilẹ̀ Amerika fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ gbàjọba kan Donald Trump
January 6 hearing: Ilé aṣòfin Ilẹ̀ Amerika fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ gbàjọba kan Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii Ile Aṣofin lorilẹede Amerika ti fihan pe Aarẹ tẹlẹri, Donald Trump lo ṣokunfa ikọlu to waye ni Capitol ni Ọjọ Kẹfa, Oṣu Kẹfa, ọdun 2021.
Igbakeji adari ajọ iwadii naa, Liz Cheney ni Trump lo fi ina si idi iṣẹlẹ naa.
Ohun to ṣẹlẹ nigba naa nipe awọn ololufẹ Aarẹ Donald Trump wa fẹhọnuhan pẹlu awọn ohun ija pe eru ni idibo to gbe aarẹ Joe Biden de ipo aarẹ.
Awọn alatilẹyin Trump ọhun ṣe ikọlu lasiko ti awọn aṣofin n dibo lati fi ontẹ lu idibo to gbe aarẹ Joe Biden ti ẹgbẹ oṣelu Democrat wọle.
Lẹyin ọdun kan ti iwadii ti n waye ni Ile Igbimọ Asofin ni wọn gbe awọn fidio to fi ẹri han pe otitọ ni aarẹ Donald trump lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Iwadii ti wọn ṣe afihan rẹ lori TV naa waye lasiko ti ọpọlọpọ eniyan yoo ni anfaani ati wo o ni ile .
Wọn ṣafihan bi Olotu eto idajọ lasiko aarẹ Trump ṣe kilọ fun un pe ko ye pa irọ pe eru ni idibo naa, ati pe awọn ọrọ rẹ ko fi idi mulẹ.
O ni ko ṣeeṣe ki wọn kọ lati gbe ijọba silẹ nitori ẹni to wa lori oye ko gbagbọ wi pe oun kuna ninu idibo sipo aarẹ naa lai si ẹri to daju.
Bakan naa ni wọn safihan ẹri ọmọ Trump Ivanka nibi to ti n sọ fun olotu eto idajọ tẹlẹri naa pe oun gba bi o ṣe sọ fun baba oun ko yẹ pa irọ pe eru wa ninu idibo to gbe aarẹ Joe Biden wọle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ niṣe ni awọn eniyan ke ‘haa’ nigba ti wọn gbọ ohun Trump nibi ti o ti sọ wi pe ki wọn yẹgi fun Mike Pence lo tọ sii.
Ohun to ṣẹlẹ nipe awọn afẹhọnuhan naa ti n pe fun ki wọn yẹgi fun igbakeji aarẹ tẹlẹri naa, Mike Pence nitori o buwọlu idibo to gbe aarẹ Biden wọle naa, ti Trump si fesi pe yiyẹgi fun lo tọsi.
Ẹmi agbofinro kan ba iṣẹlẹ naa lọ, ti iyawo rẹ si sọ wi pe titi aye ni oun ko le gbagbe iṣẹlẹ to mu ẹmi ọkọ oun lọ.
Ki igbẹjọ naa to bẹrẹ ni Trump ti n kede pe irọ ati ẹbu ni igbẹjọ Ile Igbimọ Aṣofin naa.















