Ikọlù,APC, SDP Ekiti 2022: Èèyàn kàn kú,ẹgbẹ́ méjèèjì tako ará wọn

Oríṣun àwòrán, Facebook/Segun Oni/Biodun Oyebanji
Ni bo ṣe ku ọjọ diẹ ti idibo Gomina ipinlẹ Ekiti yoo waye, awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress,APC ati Social Democratic Party, SDP ti n gbena woju ara wọn ninu ikọlu eyi to mu ṣebi ẹni da omi alaafia ilu ru.
Iroyin to deti igbọ wa sọ pe eeyan kan ti padanu ẹmi rẹ latari ikọlu to waye lọjọ Abamẹta ni Ekiti ti ibọn ba eeyan meji ti aimọye awọn mii si farapa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti Sunday Abutu to ba akọroyin wa sọrọ ni awọn ti ribi da alaafia pada lori ikọlu to waye yi ati pe lootọ ni awọn kan ṣe ikọlu si ara wọn.
Bawo ni laasigbo naa ṣe bẹ silẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/biodunaoyebanji
Lasiko oṣelu bayi, igun ti ọrọ ba kan a maa sọ pe awọn kọ lawọn jẹbi ati pe jẹjẹ lawn n lọ ki awọn alatako to dojuija kọ awọn.
Bẹẹ lọrọ ṣe fẹ ri ninu ikọlu yi to waye ni ilu Itaji Ekiti lọjọ Abamẹta.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni wahala bẹ silẹ nigba tawọn janduku kan ṣe ikọlu si awọn alatilẹyin Gomina tẹlẹ ri Segun Oni ti ẹgbẹ oṣelu SDP.
Ninu esi to fọ lori iṣẹlẹ yi, ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ SDP Bimbo Daramola naka alebu si awọn kọlọrọsi eeyan kan pe wọn n gbiyanju lati gbegi dina ipolongo Segun Oni nitori pe ẹru n ba wọn ka ma baa wọle ipo Gomina.
Ni idahun si ọrọ yi awọn ti igun Biodun Oyebanji ti ẹgbẹ oṣelu APC sọ pe kawọn alatilẹyin rẹ ma ṣe jẹ ki awọn kan mu inu bi wọn lasikoipolongo yi.
Bẹẹ ni ẹgbẹ naa sọ pe awọn to n polongo labẹ asia SDP lo wa nidi iku arakunrin ọmọ ẹgbẹ wọn kan,iyẹn Tope Ajayi ti wọn yinbọn pa lasiko ikọlu to waye.
Yatọ si pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, o tun jẹ ọmọ ẹgbẹ awakọ Road Transport Employers Association of Nigeria,RTEAN.
Awọn ẹgbẹ awakọ, bawo lọrọ ṣe kan wọn
Arakunrin kan ti iroyin sọ pe o padanu ẹmi rẹ nigba tawọn alatilẹyin ẹgbẹ mejeeji kọlu ara wn jẹ ọmọ ẹgbẹ APC to si tun jẹ awakọ la ẹgbẹ RTEAN.
Gẹgẹ bi alaye akọroyin wa to wa nibẹ, o ni pupọ awọn awakọ yi a maa ṣe atilẹyin fun ijọba to wa lori oye iyẹn ijọba APC.
Awọn awakọ taa n wi yi tori iku ọkan lara awọn ọmọ wọn Tope Ajayiṣe iwọde ni ọjọ Aiku ti wọn si ti oju ọna pa lawọn agbegbe bi Ijigbo, Odo-Ado, Okeyinmi, Atikankan ati Ajilosun.
Lasiko iwde wọn yi, wọn ko nkan ija oloro lọwọ ti wn si kọdi awọn ero ati awakọ lati gba oju ọna.
Ọpẹlọpe awọn agbofinro bii ikọ ọmọ ogun ati ajọ ori lalakan fi n sọri Civil Defence ati awọn ọlọpaa to gba oju ọna Ijigbo, Atikankan, Basiri, Ajilosun ati Ilawe ni ilu Ado ni ko jẹ ki ikọlu mii tun waye.












