'A ti ní òye gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ìkọlù ìjọ Kátólíìkì Owo, àmọ́ ...'

Àkọlé fídíò, Owo attack: Kìí ṣe pé ìjọba àti Ọlọ́pàá fọwọ́ lérán, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ tú iṣu dé ìsàlẹ̀

"Ẹ ò kàn lè máa ṣa èèyàn káàkiri lónìí, lọ́la pé àwọn ló ṣe ìkọlù yìí".

Alukoro Ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ ti wọn n gbe lori ikọlu to waye ni ijọ Katoliiki ilu Owo.

Ọgbẹni Olumuyiwa Adejobi ni nkan buruku ni nkan to ṣẹlẹ yii gbogbo awọn si lawọn kọ ọ tori iwa ẹranko ti ko daa ni lawujọ.

"Bí ajá bá pé ogún ọdún láyé, ẹran ogun ni o! Gbogbo awọn to ṣe iṣẹ yii ni Owo, wọn o ni lọ".

Bakan naa lo fesi si awọn eeyan ti wọn n sọ pe wọn joko tẹtẹrẹ lori ọrọ naa pe awọn ti ni oye gbogbo nkan to ṣẹlẹ, amọ wọn gbudọ ṣe iwadii kikun.

"Kii ṣe pe ka maa ṣa eeyan kiri lọtun losi, a gbudọ rii daju pe awọn to ṣe iṣẹ ibi yii gangan la mu".