Osinachi Nwachukwu n wọ káà ilẹ̀ sùn lónìí, ètò ìsìnkú ìkẹhìn ti bẹ̀rẹ̀!

Osinachi Nwachukwu

Gbajugbaja olorin ẹmi ọmọ Naijiria Osinachi Nwachukwu yoo w kaa ilẹ sun lonii ọjọ Abamẹta ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kẹfa ọdun 2022.

Eto isinku oloogbe olorin naa ti ṣaaju bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹfa nilu Abuja.

Osinachi jẹ Ọlọrun nipe ni ọjọ Kẹjọ oṣu Kẹrin ọdun 2022 amọ ọrọ ohun to ṣokunfa iku rẹ ko tii ye ẹni kẹni ti ọrọ naa dẹ ṣi wa nile ẹjọ bayii.

Awọn ọlọpaa n ba Ọgbẹni Peter Nwachukwu, ọkọ oloogbe naa wọ ẹjọ lọwọlọwọ.

Ilana bi wọn ṣe n sinku Osinachi ree

Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, PETER NWACHUKWU

Ẹbi Osinachukwu gangan lo n ṣeto isin ikẹhin fun ọmọ wọn.

Gbajugbaja olorin ẹmi naa yoo wọ kaa ilẹ sun ni ọjọ Ẹti Karundinlọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 2022.

Ilana isinku rẹ bẹrẹ ni ọjọ Kọkanlelogun oṣu Kẹfa ni ilu Abuja.

Ọpọlọpọ eto naa ti waye ni Abuja amọ inu agbala baba Osinachi ni agbegbe Umuaku Central School, ilu Isochi nipinlẹ Abia ni wọn yoo sin in si.

Eyi yoo jẹ lẹyin ti wọn ba ti pari isin orin alẹ, aṣalẹ adura ati orin iyin.

Ohun gbogbo to yẹ koo mọ nipa iku Osinachi ree

Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, PETER NWACHUKWU

Osinachi Nwachukwu jẹ ilumọọka olorin Kristẹni ti ọpọlọpọ fi orin to kọ “Ekwueme” daa mọ.

Lẹyin iku rẹ ni iroyin to lu jade sita pe wọn fẹsun kan ọkọ rẹ pe oun lo luu titi to fi ku.

Awọn mọlẹbi oloogbe - iya, ibeji rẹ atawọn aburo rẹ, ọrẹ atawọn mii fẹsun kan pe ọkọ rẹ maa n na a.

Amọṣa to fi mọ Ọlọpaa ati ile ẹjọ, ko si ẹnikẹni to tii fi aridaju eyi han sita.

Iku rẹ wu ibinu jade lọkan awọn eeyan kaakiri agbalaaye tori o jẹ iyalẹnu.

Ijọba da sii

Ile Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, NIGERIA MINISTRY OF WOMEN AFFAIRS

Lasiko ti awọn eeyan n ṣe ibẹwo ibanikẹdun si ile oloogbe gbajugbaja olorin ẹmi, Osinachi Nwachukwu ni ile rẹ to wa ni agbegbe Aco Estate, Abuja ni Minisita fun ọrọ obinrin ni Naijiria, Dame Pauline Tallen sọrọ pe bo tilẹ jẹ pe iroyin sọ pe oloogbe olorin naa wa nile iwosan fun aisan jẹjẹrẹ ọna ọfun ṣaaju iku rẹ, awọn nkan to jade lori ayelujara fihan pe iwa ipa ninu ile n ṣẹlẹ sii.

Nigba naa ni Tallen beere fun nkan meji lorukọ gbogbo obinrin Naijiria ati awọn iya:

*Idajọ ododo fun oloogbe to kọ orin Ekwueme ti wọn fi ẹ́=su kan pe iwa ipa latọdọ ọkọ rẹ lo fa iku rẹ.

*Aabo to peye fun awọn ọmọ ti oloogbe naa fi silẹ.

Ọlọpaa fi panpẹ ofin mu ọkọ rẹ Peter Nwachukwu

Peter ati Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ni ọjọ Kọkanla oṣu Kẹrin ni awọn Ọlọpaa fi aridaju han pe awọn ti mu ọkọ oloogbe olorin ẹmi naa.

Alukoro Ọlọpaa ilu Abuja, DSP Josephine Adeh lo fi eyi sita fun BBC.

O fi kun un pe awọn n ṣe iwadii lọwọ, bẹẹ si ni o ti n foju ba ile ẹjọ bayii.

Bakan naa ni ọlọpaa sọ pe awọn fi ofin mu u lẹyin ti arakunrin oloogbe naa wa fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.

Ki lo ni lati mọ nipa Osinachi Nwachukwu

Osinachi Nwachukwu

Oríṣun àwòrán, Peter Nwachukwu

Ṣaaju iku rẹ, olorin ni Osinachi, akọrin si tun ni to di gbajugbaja nitori orin Ekwueme ti o pawọpọ pẹlu olorin mii Prospa Ochimana kọ.

Orin naa ti ni o le ni eeyan mọkanlelaadọrin miliọnu to wo o ni Youtube.

Bakan naa, Osinachi ti kọrin ninu awọn orin bii Nara Ekele pẹlu Pasitọ ijọ rẹ, Paul Eneche ati “You no dey use me play” pẹlu Ema. Bakan naa lo ti gbe orin tirẹ jade, “God of all Power”.

O saba maa n kọ orin ni ede rẹ, Igbo amọ ko sẹni ti kii ranti ọrun to ba n kọ orin tẹkun tẹkun.

Ẹni ọ̀dun mejilelogoji ni o fi aye silẹ to si fi ọmọ mẹrin ati ọkọ rẹ saye lọ.