Ìbejì olórin ẹ̀mí Osinachi jẹ́rìí nílé ẹjọ́ níbi ìgbẹ́jọ́ ọkọ rẹ̀, Peter Nwachukwu

Aworan Osinachi ati asia Ileejo

Oríṣun àwòrán, Google

Ibeji olorin ẹmi nni to papoda, Osinachi Nwachukwu ti ni ohun to pa ekeji oun ni bi ọkọ rẹ ṣe ma n naa.

Ibeji rẹ naa ti orukọ rẹ n jẹ Amarachi Eze sọ fun ileẹjọ giga ni ilu Abuja pe;

‘’Bi ọkọ ekeji mi ṣe ma n naa lo fa iku rẹ kii ṣe aisan ọgbẹ inu tabi aisan jẹjẹrẹ’’

Ẹsun oniga mẹtalelogun ni ọkọ Osinachi, Peter Nwachukwu n koju lori lilọwọ ninu iku iyawo rẹ.

Bio tilẹ jẹ pe ọkọ naa ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, ileẹjọ ni ko lọ si ẹwọn ni Kuje titi igbẹjọ rẹ yoo fi pari.

Ekeji Osinachi to jẹ olorin ẹmi naa ni ẹlẹri kẹta ninu ẹsun ipaniyan ti ijọba Naijiria pe mọ ọkọ Osinachi.

O salaye pe nigba ti ẹgbọn rẹ wa ni ileewosan ni ọkọ rẹ wọle lati sọ fun un pe ko ni aisan jẹjẹrẹ nitori ayẹwo ti ṣafihan bẹẹ.

‘’Inu ẹkeji mi si dun, ohun ti mo fẹ ni idajọ otitọ lori bi ọkọ rẹ ṣe ma n na a bi ẹran’’

‘’Igbakigba to ba fe na a, niṣe ni yoo fun un ni ẹṣẹ ni gbogbo ara ti yoo si fun un ni ipa ni aya’’

‘’Igba to wa ninu oyun akọkọ, o pe mi pe igbalẹ ni ọkọ rẹ ma fi n na a, ti ko si ni fun un ni ounjẹ’’

‘Ọkọ Osinachi le mi jade kuro ni ileewosan to wa nitori mo wa ki i– Ibeji Osinachi

Lasiko ifọrọwanilẹnuwo, ekeji Osinachi naa ni Osinachi pe oun pe aya n dun oun, ti oun si lọ si ile iwosan ijọba ti ilu Abuja nibi to ti n gba itọju.

Nigba ti ọkọ rẹ ri oun lo bere pe kini oun wa, to si ni o lalejo wi pe oun ko le wọle.

O ni itagbangba ni oun duro si titi di alẹ ki oun to ri ekeji oun.

Ọjọ keji ni ọkọ rẹ ni ki oun kuro nibẹ ni alẹ, ti Osinachi da sii, amọ to si pariwo lee lori.

Lẹyin naa ni Osinachi bẹbẹ pe ko lo ba oun wo awọn ọmọ, to si bẹrẹ si ni sunkun amọ ti ọkọ rẹ ko jẹ ki wọn ri awọn ọmọ naa.

Osinachi ba ikeji rẹ ja nitori ọkọ rẹ ti iyẹn si pada si ilu wọn.

Lẹyin ọjọ diẹ ni wọn pee pe ekeji rẹ ti papoda.

Awọn ọmọ Osinachi yoo sọ ohun ti wọn mọ nipa iku iya wọn

Nibayii ileẹjọ ti gba ki awọn ọmọ Osinachi wa ṣe ẹlẹri amọ wọn yoo da abo bo wọn gẹgẹ bi ọmọde.

Ileẹjọ ko ni gba awọn ti ko ba pọndandan ki wọn wa ni ileẹjọ laaye lati wa nibẹ, bii awọn oniroyin.

Bakan naa ni wọn yoo fi aṣọ bo wọn loju ti wọn ba n sọrọ lati da abo bo wọn.

Ọdọ iya iya wọn ni wọn wa ni Enugu ti mama si ni inu oun dun lati tọju wọn amọ ibanujẹ nipe ọmọ oun ko si ni aye mọ.