BBC Yorùbá: Ìbò rẹ ni agbára rẹ, jáde lọ dìbò
Gẹgẹ bii ileesẹ igbohunsafẹfẹ to pegede, ileesẹ BBC News Yoruba ko gbẹyin nidi riran awọn ọmọ Naijiria leti ojuse wọn nidi eto idibo.
A n rọ awọn araalu lati mase ri eto oselu bii ayo ẹlẹgbin nitori ibo wa ni agbara wa lati yan asaaju ti a fẹ.
A si tun n parọwa sawọn eeyan lati mase ta ibo wọn nitori ohun buruku ni asa ‘Dibo, ko sebẹ’, ko si yẹ ka maa bawọn kopa ninu rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Aranṣọ, olórin àti àwọn mì í ti ko fẹ́ kí ìdìbò kásẹ̀ nílẹ̀ ní Nàìjíríà
- Ìjìyà Amosun n dúró dè é di ẹ̀yìn ìdìbò - APC
- Inec: Kò sí ìká tí o kò lè fí dìbò, ṣáà tí tẹ̀ ẹ́ sójú ẹ dáadáa
- Ìjọba àpapọ̀ fẹ́ dènà lílo ayélujára àti ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lọ́jọ́ ìbò - Fayose
- Bí ọkọ mi bá fìdírẹmi, màá gbà f'Ọ́lọ́run - Titi Abubakar
- Ajọ UN ati INEC gbé ìlanilọ́yẹ̀ lọ Kwara
- Ọ̀rọ̀ bọ́ lórí òjò òkò tó rọ̀ lé àwọn asaájú APC l‘Abeokuta
- Ẹfunroye Tinubu - Ògbóǹtagí oníṣòwò, olówò ẹrú àti afọbajẹ
- Olúwa mi, n kò jẹ̀bí ẹ̀sùn àjẹbánu - Babachir Lawal
A tun n rọ awọn eeyan wa lati ta kete siwa jagidi jagan nitori ohun buruku ni, ibo la si fẹ ki wọn di, a ko fẹ ki wọn da ilu ru.
BBC News Yoruba wa n kesi yin pe kẹ jade wa dibo, kẹ ran ika atanpako yin nisẹ, nitori ibo wa ni agbara wa.