2019 Elections: PDP ní àmì pé ayé ti kọ ìjọba Buhari ní wọn ṣe ju òkúta lù wọ́n

Oríṣun àwòrán, @ledon_ng
Ọpọ eeyan lo ti n sọ ero ọkan lori isẹlẹ to waye nilu Abẹokuta lọjọ Aje nigba ti awọn eeyan kan to peju sibi ipolongo ibo, bẹrẹ si ni sọ oko ati ọra omi lu awọn asaaju ẹ́ẹgbẹ oselu APC.
Aarẹ Muhammadu Buhari gan wa nikalẹ lasiko ti isẹlẹ ọhun waye.
Nigba to n fesi lori isẹlẹ yii, ẹgbẹ alatako gboogi ninu idibo to n bọ, PDP, ninu atẹjade kan to fisita ni, o yẹ ko ye ẹgbẹ oselu APC pe ami pe aye ti kẹyin si ẹgbẹ oselu naa, ni isẹlẹ naa jẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo fídíò bí wọ́n ṣe sọ nǹkan lu àwọn adarí APC l'Abẹokuta
- Day 19: Wo ohun àràmàndà tí àwọn olósèlú máa ń ṣe lásìkò ìbò #BBCNigeria2019
- Àrà méèrírí , ẹ wo ọkùnrin tí eegun rẹ̀ rọ̀ bíi rọ́bà, tó ń ká bíi ẹja
- Samuel Ajayi Crowther, òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó gbé èdè Yoruba lárugẹ
- Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
- Clinton fagilé àbẹ̀wò rẹ̀ sí Nàìjírìa tó yẹ kó wáyé lónìí
PDP ni o yẹ ka kiyesi pe awọn eeyan naa ju oko lu Buhari lẹyin ọjọ kan soso pere ti ipolongo ibo waye nipinlẹ Zamfara, nibi ti Buhari ti n ru awọ̀n eeyan ibẹ lọkan lati dara pọ ẹgbẹ APC ninu ete lati da rogbodiyan silẹ lasiko ibo to n bọ.
Ẹgbẹ oselu alatako naa ni, awọn eeyan ipinlẹ́ Ogun ati Naijiria lapapọ ti kọ ijọba aarẹ Muhammadu Buhari, nirori irora, iṣẹ, oṣi, iwa ajẹbanu ati itajẹsilẹ to n waye laarin ọdun mẹrin to fi dari Naijiria.
Sugbọn loju opo ikansira ẹni lori ẹrọ ayelujara, oju ọtọtọ ni awọn eeyan fi wo isẹlẹ naa.
@mynameisgafar loju opo Twitter rẹ ni, oun foju laifi wo iwa awọn eeyan to sọ okuta lu aarẹ Buhari. O ni bi o tilẹ jẹ pe oun ko nifẹ rẹ, sugbọn o yẹ ka bu ọwọ nla fun nitori ipo nla to di mu, ibi ti a sa pe ni ori, ẹnikan kii fi ibẹ tẹ ilẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
@Chizybae, lero tiẹ ni ohun ti yoo sẹlẹ ree ti eeyan ba ko ilu sinu isẹ ati ọwọn gogo ọja.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
@kcnaija loju opo Twitter tiẹ ni, o yẹ ka takete si ohunkohun to lee farajọ iwa jagidi jagan lasiko ibo to n bọ, paapa ninu eto oselu wa. Ko si baa ti korira igun keji si, ti a ko fara mọ wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3