NIgeria 2019 Elections: Clinton ní kí wọn má fojú òṣèlú wo àbẹ̀wò òun

Bill Clinton

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọrọ idibo Naijiria

Aarẹ orilẹede Amẹrika tẹlẹ ri, Bill Clinton ti fagile abẹwo rẹ si orilẹede Naijiria.

Igbimọ to n ri si eto alaafia ṣaaju eto idibo gbogbogbo ọdun yii lo fiwe pe Clinton wa si Naijiria.

Ọgbẹni Clinton nireti wa tẹlẹ pe yoo sọrọ iyanju nibi eto fifi ọwọ si iwe adehun lori bi alaafia yoo ṣe jọba lasiko idibo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, BBC Nigeria 2019: Lekan Kingkong ní a kò fẹ́ ìtàsílẹ̀ àti ikú ọ̀dọ́ lásìkò ìbò

Ọjọ Iṣẹgun ọjọ Kejila si Ọjọru ọjọ Kẹtala osu Keji ọdun 2019 si leto naa yoo waye.

Agbẹnusọ fun aarẹ ana ni Amẹrika naa, Angel Urena, to fọrọ naa lede sọ pe, wọn fagile abẹwo Clinton ọhun tori pe awọn kan le fẹ fi ọrọ oṣelu wo abẹwo rẹ.

O ṣalaye pe, Ọgbẹni Clinton yoo ba Aarẹ Muhammadu Buhari, to jẹ oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ APC, ati Atiku Abubakar to n dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ PDP sọrọ.

Bakan naa ni yoo tun ba olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, ọgagun fẹyinti Abdulsalam Abubakar sọrọ lọsẹ yii, lori igbesẹ rẹ.