#BBCNigeria2019: Ajọ UN ṣètò ìlanilọ́yẹ̀ láti dènà màgòmágó ìbò

Àwọn olukopa nibi ipade

Ajọ to n wa idagbasoke ilẹ adulawọ labẹ ajọ isọkan orilẹede agbaye, UNDP pẹlu ifọwọsowọpọ ajọ eleto idibo nil wa, INEC ati igbimọ ajọ to n wa ifẹsẹmulẹ alafia, ti ṣe agbekalẹ ilanilọyẹ fun àwon ẹgbẹ oṣelu ni Ipinlẹ Kwara.

Ninu ọrọ rẹ, aṣoju akowe agba fun ajọ UN, Mohamed Ibn Chambas salaye pe, wọn ṣe agbekale eto naa lati rii daju pe, ko si magomago ninu idibo to n bọ yii.

Chambas ni ipo Naijiria ṣe pataki nilẹ Afrika ati ni agbaye, eyi lo fi ṣe pataki ki orilẹede yii ṣe idibo ti ko ni mu wahala wa, ti yoo si lọ ni irọwọrọsẹ.

Mohammed Ibn Chambas
Àkọlé àwòrán, Aṣoju akowe agba fun ajọ UN, Mohamed Ibn Chambas ni ko gbọdọ si magomago ninu idibo 2019

Ninu ọrọ rẹ, ọga agba eleto idibo ní ipinlẹ Kwara, Malam Garba Attahiru lasiko to n ba awọn eniyan sọrọ salaye pe, gbogbo awọn oloṣelu gbọdọ ṣe awari ara wọn.

O fikun pe o yẹ ki wọn si maa fi eri ọkan ṣe lasiko idibo. O fi kun pe awọn n ṣe aṣepọ pelu gbogbo akojọpọ awọn eleto aabo ki eto aabo le kẹsẹ jari.

O ni laisi alafia, idibo ko le waye, o si ṣe pataki ki awon obi b'oju to awọn ọmọ wọn daradara ki awọn oloṣelu maa baa lo won lo lasiko ibo.

Eto ipade alafia naa to waye ni ilu ilorin, ni awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu, CAN, IPAC, UN, awọn iyalọja, aṣoju awọn eleto aabo pẹlu awọn lọbalọba peju si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ọ̀gá àgbà Fásitì Eko sọ ohun tí àwọ́n obìnrin lè fi tayọ