#BBCOGUNDEBATE: Kashamu, Bankole àti Abiodun kọ̀ láti kópa nínú ìpàdé ìtagbangba BBC

Dimeji, Kashamu àti Abiodun
Àkọlé àwòrán, #BBCGOVDEBATE: Oludije mẹ́ta ti kò yoju síbi àperò BBC
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Àsà àti ìṣe BBC ni láti máa fún gbogbo ènìyàn ní pèpéle kan náà, ìdí niyìí tí wọ́n ṣe ti ṣáájú kọ̀wé pe gbogbo àwọn olùdíje sípò gómìnà tí àwọn ènìyàn sọ pé àwọn ń fẹ́ láti rí níbi ìpàdé ìtagbangba ìpínlẹ̀ Ogun. ẹgbẹ́ òṣèlú méje ní a pè.

PDP: Buruji Kashamu

APM: Adekunle Akinlade

ANN: Ademola Ogunbanjọ

ADP: Dimeji Bankole

APC: Dapo Abiodun

ADC: Gboyega Nasiru Isiaka

SDP: Rotimi Paseda

Àwọn olùdíje mẹ́ta ló kọ̀ tí kò wá tí wọn kò sì kọ̀wé ránṣẹ́ pé àwọn kò ni wá, àwọn olùdíje náà ni Dimeji Bankole ti ẹgbẹ́ òṣèlú ADP, Dapo Abiodun ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Buruji Kashamu ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lẹ́yin ti wọn ti sọ pé àwọn yóò yọjú.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Nínú àwọn olùdíje ti kò yọju yìí sí fi dá ilé iṣẹ́ BBC lóju titi dí alẹ ọjọ́bọ̀ pé àwọn ń bọ sùgbọn titi tí ìròyìn yìí fí ń jáde à kò ti gbọ́ ìdí ti wọn kò fi péjú síbẹ̀

Ẹwẹ, gbogbo awọn oludije to yọju lo wu awọn eniyan lori pẹlu gbogbo alakalẹ aato wọn lọlọkan o jọkan ti wọn ni awọn yoo gbe ṣe bi awọn ba di gomina ipinlẹ Ogun.