Nigeria Election 2019:El-Rufai, lọ tọwọ́ ọmọ rẹ bọ aṣọ! - Òǹwòye ìdìbò YIAGA

Nasir El-Rufai in blue attire

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Gómínà Nasir El-Rufai dá ogunlọ́gọ́ àwọn olùkọ́ ìpínlẹ̀ náà dúro l'ọdún tó kọjá

Ọpọlọpọ iriwisi lo ti n jẹ jade latari ọrọ ti gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El Rufai sọ si awọn onwoye idibo wi pe 'Onwoye kankan lati ilu okere to ba n bọ lati dasi idibo Naijiria ko ni fara re pada sile.'

Lara awọn ti wọn wi ti wọn ni ikọ onwoye idibo abẹle kan lorileede Naijiria ti orukọ wọn n jẹ 'Watching the Vote'.

Agbẹnusọ ẹgbẹ onwoye naa to jẹ eto pataki kan labẹ Yiaga Afrika, Moshood Issa sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe ọrọ ti Gomina El Rufai sọ ku diẹ kaato.

O ṣalaye pe ko si nnkankan ti awọn to wa n ṣe amojuto eto dibo fẹ jẹ lere ju pe ki eto idibo lọ ni irọwọrọsẹ.

''Lootọ lawọn onwoye ibo kan to jẹ ti abele maa n gbabọde fun awọn oloselu kọọkan ṣugbọn ni ti awọn to n bọ lati ilẹ okere wọn kii figba kan bọ ikan ninu''

Awọn ọdọ onijanduku

Oríṣun àwòrán, SEYLLOU DIALLO/AFP/GETTY

Àkọlé àwòrán, Awọn ọdọ wọnyi n fa wahala lẹyin esi idbo ọdun 2011 nilu Kano

Moshood tẹsiwaju pe awọn oloseelu ni lati ṣọra fun ọrọ to le da 'rogbodiyan silẹ laarin awọn ara ilu paapa julọ bi eto idibo ti ṣe n kan lẹkun bayi ni Naijiria.'

O ni ko yẹ ki o si ifoya kankan nipa awọn onwoye idibo nitori pe INEC yoo ti saaju ṣe agbeyẹwọ wọn ki wọn to gba iyọnda lati wa kopa ninu eto idibo.

Moshood rọ awọn agbofinro naa lati kilọ fun awọn oloṣelu lati tọwọ ọmọ wọn basọ pẹlu ọrọ to le da wahala silẹ laarin ilu.

Ọrọ wa lori ọrọ kobakungbe ko yi pada

Aworan Adele Ọga ọlọpaa tuntun

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Àkọlé àwòrán, Adele Ọga ọlọpaa tuntun ni iṣẹ nla niwaju pẹlu idibo 2019 to n bọ lọna

Adele Ọga ọlọpaa tuntun lorileede Naijiria Mohammed Adamu naa ti da si ọrọ to wa nilẹ yii.

Nigba ti o n sọrọ nibi apero kan ti ajọ eleto idibo lorileede Naijiria INEC ṣagbatẹru rẹ nilu Abuja, Mohammed sọ pe ipinu ile iṣẹ ọlọpaa lori ọrọ kobakungbe ko yatọ si tẹyin wa.

O tẹnumọ pe ipinu yii ni idahun si ibeere tawọn akọroyin bi i nipa ọrọ Gomina El Rufai to sọ.