Olorì Aláàfin kan kú lẹ́yìn oṣù kejì tí Ọba Adeyemi wàjà

Lẹ́yìn oṣù méjì tí Aláàfin ìlú Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta wàjà, ọ̀kan lárá àwọn Olorì àgbà, Olorì Kafayat Adeyemi náà kí dúnìyàn wí pé ó dìgbà.
Nígbà tó ń fìdí ikú náà múlẹ̀ fún BBC News Yorùbá, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Aláàfin, ọmọọbabìnrin Arewa Adeyemi ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni Olorì náà kú sí.
Ọmọọbabìnrin Adeyemi ṣàlàyé pé ojú orun ní Olorì Kafayat wà tí ọlọ́jọ́ ti dé bá láì ṣe àárẹ̀ tàbí ṣe àìsàn kankan.
“Kò sí nǹkankan tó ṣe wọ́n kòdá wọ́n ti ṣe eré amárayá òwúrọ̀ tí wọ́n máa n ṣe ni ojoojúmọ́ kí wọ́n tó papòdà.”
Ta ni Olorì Kafayat Adeyemi?
Olorì Kafayat Adeyemi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olorì àgbà fún Aláàfin Adeyemi tó darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀ nínú oṣù Kẹrin, ọdún 2022.
Olorì Kafayat ló kọ́kọ́ bí ìbejì fún Aláàfin Adeyemi.
Bákan náà ló jẹ́ ìyá ọmọọba Adebayo Adeyemi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí “D’gov” tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ní ìpínlẹ̀ Oyo.
Òun náà ló kọ́kọ́ bí ọmọ ọkùnrin fún Kábíyèsí.
Ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn ni olorì Kafayat kó lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lọ́dọ̀ Táyé, ìkan nínú àwọn ìbejì tó bí fún Aláàfin.















