Tinubu ló sanwó ta fi gbé òkú Moji Olaiya wá láti òke òkun - Jide Kosoko

Oríṣun àwòrán, screenshot
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ ẹni kò ní ṣe ìdí bẹ̀bẹ̀rẹ̀ kákó ìlẹ̀kẹ̀ sídìí ọmọ ẹlòmíràn.
Nínú ọ̀sẹ̀ yìí ni fídíò kan gba orí ayélujára tó ṣàfihàn àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ nínú eré tíátà Yorùbá níbi tí wọ́n ti ń ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje sípò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.
Lára àwọn tó wà nínú fídíò náà ni Jide Kosoko, Adebayo Salami, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí ọga Bello, Foluke Daramola, Fausa Balogun, Yinka Quadri, Taiwo Haasan Ogogo, Iya Awero àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Fídíò yìí ló ti ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí ayélujára pàápàá láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń sọ wí pé kò yẹ kí àwọn àgbà òṣèré máa fi ipò wọn ṣe ìpolongo fún àwọn olóṣèlú.
Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí Jide Kosoko ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ní ipa tí Tinubu ti kó nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré tíátà kò ṣé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá.
Kosoko ní Tinubu kìí kan ṣe olórí lásán bíkòṣe aláàánú, tó fi ọrọ̀ rẹ̀ mọ àwọn òṣèré tíátà náà.
Ó ní ìdí nìyí tí àwọn náà fi ń gbá rùkù tìí, tí àwọn sì ń ṣe ìpolongo fún-un.
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni Asiwaju ti fa lọ́wọ́ sókè nínú eré tíátà pàápàá àwọn tó bá ní ìpèníjà ìlera”.
“Nígbà tí Moji Olaiya kú sí orílẹ̀ èdè Canada, Tinubu ló san gbogbo owó tí wọ́n fi gbé òkú rẹ̀ wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.”
Bákan náà ló ní ìyàwó Tinubu náà ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfàní fún ọ̀kan-ò-jọ̀kan ènìyàn nínú eré tíátà tí àwọn kò le kà tán.
Tinubu ló kọ́kọ́ fún wa ní ilẹ̀ láti kọ ilé sinimá
Fídíò yìí ló ti ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórí ayélujára pàápàá láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń sọ wí pé kò yẹ kí àwọn àgbà òṣèré máa fi ipò wọn ṣe ìpolongo fún àwọn olóṣèlú.
Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí Jide Kosoko ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ní ipa tí Tinubu ti kó nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré tíátà kò ṣé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá.
Kosoko ní Tinubu kìí kan ṣe olórí lásán bíkòṣe aláàánú, tó fi ọrọ̀ rẹ̀ mọ àwọn òṣèré tíátà náà.
Ó ní ìdí nìyí tí àwọn náà fi ń gbá rùkù tìí, tí àwọn sì ń ṣe ìpolongo fún-un.
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni Asiwaju ti fa lọ́wọ́ sókè nínú eré tíátà pàápàá àwọn tó bá ní ìpèníjà ìlera”.
“Nígbà tí Moji Olaiya kú sí orílẹ̀ èdè Canada, Tinubu ló san gbogbo owó tí wọ́n fi gbé òkú rẹ̀ wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.”
Bákan náà ló ní ìyàwó Tinubu náà ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfàní fún ọ̀kan-ò-jọ̀kan ènìyàn nínú erér tíátà tí àwọn kò le kà tán.