Ọlọ́pàá mú pásítọ̀ tó kó àwọn ọmọ ìjọ pamọ́ sí àjà ilẹ̀ l'Ondo, Ó ní oṣù kẹsàn án ni 'Jesu' yóò dé

Aworan awọn eeyan lagọ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, screenshot/twitter

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ alufa ijọ kan nilu Ondo ati igbakeji rẹ tim wọn fi itanjẹ ko awọn ọmọ ijọ ni papa mọra pe Jesu yoo de ni oṣu kẹsan ọdun yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti ṣalaye ọrọ lori awọn ti wọn ko nni ijọ naa pe wọn kii ṣe ọmọde nikan.

Alukoro ileeṣẹ ọ̀lọpaa nipinlẹ Ondo, SP Ọdunlami ṣalaye pe alufa ijọ naa sọ fun awọn ọmọ ijọ naa pe aye yoo parẹ loṣu kẹsan an ọdun 2022, nitori naa ni gbogbo awọn ọmọ ijọ naa fi ko ara jọ pọ si ijọ naa ni ireti ipadabọ Jesu.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni eeyan mẹtadinlọgọrin ni wọn ko ninu ijọ naa ninu eyi to ni awọn agbalagba lo pọ julọ laarin wọn.

“Ọpọ awọn ọmọde miran ni wọn ti fi fi ile wọn silẹ lati bii oṣu karun un lẹyin ti pasitọ naa ti sọ fun wọn pe Jesu yoo de loṣu kẹsan ko si si idi fun wọn lati kawe mọ.”

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ni iwadi ti bẹrẹ, bẹẹni pasitọ naa ati igbakeji rẹ ti wa ni atimọle awọn ọ̀lọpaa.

Ọlọ́pàá ṣàwárí àwọn ọmọ ìjọ lábẹ́ àjà ilẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ọpọlọpọ awọn ọmọde ni wọn ri ninu aja ilẹ kan nile ijọsin kan lagbegbe valentino nilu Ondo nipinlẹ Ondo lalẹ ọjọ Ẹti.

Gẹgẹbi ohun ti a gbọ, awọn ajinigbe lo ji awọn ọmọde naa gbe ti wọn si fi wọn pamọ sinu aja ilẹ nile ijọsin naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, SP Funmilayọ Ọdunlami ṣalaye fun BBC pe awọn ọlọpaa ti wa lagbegbe naa bayii lati tan ina wadii ohun to ṣẹlẹ nibẹ gan an.

Amọṣa awọn iroyin atọwọdọwọ ti a gbọ lori iṣẹlẹ naa fi yeni pe, awọn ọmọde ti wọn ba nibẹ to aadọta, bi o tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ko tii fi idi iye awọn ọmọ tyi wọn ba nibẹ mulẹ.

Ninu fidio kan to n ja ranyin lori ayelujara, awọn ọmọde naa wa ninu ọkọ ọlọpaa kan eyi to gbe wọn lọ si agọ ọlọpaa.

Amọṣa alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa ni wọn ti n ko awọn ọmọde naa lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa nilu Akurẹ.

Aworan ọrọti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo fi soju opo twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot/twitter

Ninu ọrọ to fi sita loju opo twitter rẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ SCID ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni wọn rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati simẹdọ ki wọn si gba alaafia laaye.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, laipẹ yii ni iṣẹlẹ manigbagbe waye nile ijọsin kan nilu Ọwọ nipinlẹ Ondo kan naa nibi ti awọn agbebọn ti ṣeku pa eeyan ti ko din ni ogoji.