Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo di awakọ̀ kẹ̀kẹ́ Márúwá ní Abeokuta

Oríṣun àwòrán, @danielsync/@themomenttographer
Kayefi ati awada lo jẹ fun ọpọ olugbe ilu Abẹokuta ni ipinlẹ Ogun lọjọ Abamẹta nigba ti wọn ri aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to n wa kẹkẹ Maruwa kiri igboro nibẹ.
Yatọ si pe riri oloye Ọbasanjọ ti ọpọ mọ si Ẹbọra Owu ninu kẹkẹ Maruwa ṣe ọpọ ni Kayefii, iṣọwọ bi o tun ṣe fi n ko ero kaakiri igboro ko ṣai maa pa ọpọlọpọ awọn to rii lẹrin.
Amọṣa, iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ sọ pe, ara pọpọṣinṣin ayajọ ọjọ ibi ọdun karundinlaadọrun rẹ ni eyi jẹ.
Eeyan marundinlaadọrun ni Oloye Ọbasanjọ pin kẹkẹ Maruwa fun lasiko to n sami ayajọ ọjọ ibi rẹ naa.

Oríṣun àwòrán, @DanielSync/@themomenttographer
BBC Yoruba gbọ pe lati inu ọgba ilẹ rẹ to wa ni ile ikawe aarẹ, iyẹn Olusegun Obasanjo Presidential Library to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta ni baba naa ti wa Kẹkẹ Maruwa yii, to si fi n gbe awọn ero titi de agbegbe Kutọ nilu Abẹokuta kan naa.
Awọn ọdọ inu ile ikawe aarẹ naa, Olusegun Obasanjo Presidential Library Youth Centre la gbọ pe wọn ṣagbatẹru eto ọhun.

Oríṣun àwòrán, @danielsync/@themomenttographer
Ọpọ awọn ti wọn ri Baba Ọbasanjọ nibi to ti n wa Kẹkẹ Maruwa naa lo la ẹnu silẹ, ti wọn ko le pa a de tiyanu-tiyanu, nitori ohun to jọ wọn loju gidi ni.








