Ilé ẹjọ́ ju Àlfà Isah Mustapha sí ẹ̀wọ̀n gbére f'ẹ́sùn fífipá bá ọmọ ọdún mẹ́jọ lò pọ̀ ní Eko

Ìfipábánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ilé ẹjọ́ gíga tó fi ìpínlẹ̀ Eko ṣe ibùjókòó ti rán Alfáà kan, Isah Mustapha ní ẹ̀wọ̀n gbére fẹ́sùn wí pé ó fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́jọ ní àjọṣepọ̀.

Onídàjọ́ Oshodi H. O. tó gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Keje, ọdún 2022 ní Alfa Mustapha jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ èyí tí wọ́n fi kàn-án.

Fún ìdí èyí ó ní kí ó lọ máa fi aṣọ péńpé roko ọba títí ayérayé.

Ọmọdébìnrin tí Mustapha fi ipá bá lòpọ̀ nígbà tó ń ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ ṣàlàyé wí pé nínú ilé Mustapha ló ti fi ipá bá òun lòpọ̀ nígbà tí ìyá òun rán òun níṣẹ́.

Ó ní ọdún 2017 ni ìyá òun ní kí òun lọ jíṣẹ́ fún òun àmọ́ Mustapha pe òun padà nígbà tí òun ń bọ̀ wí pé òun fẹ́ rán òun sí màmá òun náà.

“Aafa Mustapha ní kí n bá òun gba àlùbọ́sà wá lọ́dọ̀ ìyá mi tí mo dẹ̀ lọ fun ní ìsàlẹ̀.”

“Nígbà tí mo yí padà láti máa lọ ló tún pè mí padà wí pé òun kò ì tíì rán mi níṣẹ́ tán wí pé ki ń wọ ilé ilé òun wá”.

“Mi ò kọ́kọ́ fẹ́ wọ inú ilé rẹ̀ àmọ́ mi ò fẹ́ kí ó fẹjọ́ mi sun bàbá mi wí pé mò ń kọ iṣẹ́ fún òun ni mo ṣe gbà láti wọ ilé wọn.”

Ó tẹ̀síwájú wí pé nígbà tí òun wọ inú ilé rẹ̀ tán ló ní kí òun bọ́ pátá òun ṣùgbọ́n òun kọ̀ láti bọ àmọ́ tó bọ fúnra rẹ̀ tó sì bọ́ ṣòkòtò tirẹ̀ náà.

Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ọmọ náà fi kun pé lẹ́yìn ìgbà náà ni Mustapha fi ipá bá òun ní àjọṣepọ̀.

“Nígbà tí ìyá mi fẹ́ fọ aṣọ tí mo wọ̀ ni wọ́n rí ẹ̀jẹ̀ níbẹ̀ nígbà ni wọ́n tó mọ òun tó ṣẹlẹ̀ gan”

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ Mustapha ní òun kàn tọwọ́ bọ ọmọ náà ní ojú ara ni wí pé òun kò ba sùn rara.

Lẹ́yìn gbogbo ìjíròrò àti atótónu àwọn agbẹjọ́rò ni adájọ́ ju Mustapha sí ẹ̀wọ̀n gbére.