Ìjọba Eko gbé ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ tì pa lẹ́yìn ikú akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún márùn ún tó ń lùwẹ̀
Ìjọba Eko gbé ilé ẹ̀kọ́ Redeemers Nursery and Primary School tì pa lẹ́yìn ikú akẹ́kọ̀ọ́ tó ń lùwẹ̀

Oríṣun àwòrán, @THISDAYLIVE
Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe ile ẹkọ alakọbẹrẹ Redeemers Nursery and Primary School, to wa ni Ogba ti pa lẹyin ti iku akẹkọọ rẹ kan.
Kọmisọna fun eto ẹkọ, Folashade Adefisayo lo kede igbesẹ naa lẹyin iṣẹlẹ ọhun.
Igbesẹ ijọba yii ko ṣẹyin bi akẹkọọ kan ṣe ri sinu omi lasiko ti wọn n kọ oun atawọn akẹgbẹ rẹ bi wọn ṣe n luwẹ.
Adefisayo ni ile ẹkọ ọhun yoo wa ni titi pa titi ti wọn yoo fi pari iwadii lori awọn alakalẹ ile ẹkọ naa lori eto abo awọn akẹkọọ rẹ.
O ni “Iwadii yii n waye lẹyin iku akẹkọọ ọmọ ọdun marun un kan to ri sinu omi lakata ile ẹkọ naa lasiko ti wọn n kẹkọọ bi wọn ṣe n luwẹ.
“Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii ti wọn.”
“Iwadii ọọfisi to n ri si awọn ohun amuyẹ to yẹ ki ile ẹkọ ni fi han pe ile ẹkọ Redeemers Nursery and Primary School yii ko tii pari iforukọsilẹ rẹ, nitori naa, ko tii gba ontẹ ijọba.”
Gẹgẹ bii ohun ti kọmisọna naa sọ, ohun to jẹ ijọba logun ni abo awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa, eredi ree ti awọn ṣe da si ọrọ ọhun.
O ni awọn ko ni ṣi ile ẹkọ naa pada titi di igba ti awọn alaṣẹ rẹ yoo fi ṣe gbogbo iforukọsilẹ to yẹ ki wọn ṣe.
Lẹyin naa lo gba awọn obi to ni ọmọ sile ẹkọ ọhun nimọran lati foye si igbesẹ ti ijọba gbe, ki wọn si ni suuru di igba ti awọn yoo ṣi ile ẹkọ naa pada.












