Àtìmọ́lé ni Pásítọ̀ 'Ondo Church' tó kó àwọn ọmọ ìjọ pamọ́ sí àjà ilẹ̀ yóò ti ṣe ọdún iléyá

Oríṣun àwòrán, screenshot/ other
Ile ẹ̀jọ Majisireeti to n gbọ ẹjọ pasitọ ijọ The Whole Bible Church nilu Ondo, Pasitọ David Anifowoṣe, igbakeji rẹ Josiah Peter atawọn mẹta miran ti wọn fi ẹsun kan pe wọn fi tipa ko awọn eeyan kan pamọ sinu ile ijọsin wọn tun tẹsiwaju igbẹjọ lọjọ Ẹti.
Ile ẹjọ naa sun igbẹjọ rẹ siwaju di ọjọ kejidinlogun oṣu keje ọdun 2022.
Onidajọ Majisireeti Rashidat Yakubu to gbọ ẹjọ naa ṣalaye pe oun sun un siwaju lati lee fun ile ẹjọ naa laaye ati farabalẹ yẹ ẹbẹ fun beeli awọn olujẹjọ naa ti agbẹjọro wọn gbe ka iwaju ile ẹjọ naa wo.
Nigba ti igbẹjọ naa bẹrẹ lọjọ Ẹti, agbẹjọro fun olupẹjọ, Leo Ologun rọ ile ẹjọ lati wọgile abala ikarun un ati ikẹfa ẹbẹ naa, ki wọn si ri atimọle ti wọn fẹ fi awọn olujẹjọ naa si gẹgẹ bi ọna kan lati daabo bo wọn nitori inu ṣi n bi awọn eeeyan to wa lagbegbe ijọ wọn.
Amọṣa agbẹjọro fun olujẹjọ, Ọladele Ayọọla tako eyi. O ni ohun to ṣini lọna patapata ni Olupẹjọ sọ.
Pásítọ̀ 'Ondo Church' tó kó àwọn ọmọ ìjọ pamọ́ sí àjà ilẹ̀ fojú ba ilé ẹjọ́

Pasitọ ile ijọsin Whole Bible Believers Church nilu Ondo ti wọn fi ẹsun kan pe wọn ri agidi ko awọn ọmọ ijọ pamọ si ajalẹ ni wọn foju ba ile ijọ loni.
Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ondo lo pẹjọ tako alufaa ijọ The Whole Bible Church ti ọpọ mọ si "Ondo Church" Pasitọ David Anifowoṣe ati awọn mẹrin miran niwaju ile ẹjọ majisireeti kan nilu Akurẹ.
Ẹsun ifipa gbenipamọ ni wọn fi n kan awọn afurasi naa.
Kọmiṣọna feto idajọ nipinlẹ Ondo to tun jẹ agbẹjọro agba fun ijọba ipinlẹ naa, Amofin Charles Titiloye lo lewaju ikọ olupẹjọ nigba ti Amofin Oladele Ayoola si jẹ agbẹjọro fun awọn olujẹjọ.
Awọn ọlọpaa ya bo ile ijọsin kan ti orukọ rẹ n jẹ The Whole Bible Church lagbegbe Valentino nilu Ondo lọjọ Ẹti lẹyin ti arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Elizabeth Rueben pariwo sita pe awọn adari ijọ kan ti ọmọ oun nlọ ti gbe e pamọ si ahamọ wọn ko si fẹ ko ṣe idanwo aṣekagba girama WAEC.
Arabinrin naa ni ohun ti wọn n sọ fun ọmọ oun ati ọpọlọpọ awọn ọmọ ijọ to wa nile ijọsin naa ni pe Jesu yoo de ni ọdun yii nitori naa ki wọn pa gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe ti nitori bi Ọlọrun ṣe fẹẹ niyi.

Ni kete ti wọn mẹnuba ẹjọ ọun ni agbẹjoro fawọn olujẹjọ ti rawọ ẹbẹ si onidajọ Magistrate R.O. Yakubu ki o fun ohun laaye lati lọ yẹ iwe ẹsun ti wọn fi kan awọn onibara ohun wo finnifinni, leyi ti yoo gba ohun to ọjọ meji.
Ẹwẹ Magistrate Yakubu ni o wipe aaye ọjọ meji ko le yọ nitoripe ọla ni ọjọ ẹti to jẹ ọjọ iṣẹ to kẹyin lọsẹ yi ati pe isinmi lẹnu iṣẹ le wa lọjọ aje ọsẹ to n bọ.
O waa sun igbẹjọ si ọla ọjọ ẹti ọjọ kẹjọ oṣu keje ọdun yi lati fun agbẹjọro awọn olujẹjọ laaye lati le fesi si iwe ẹsun ti wọn fi kan awọn onibara rẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo SP Olufunmilayọ Ọdunlami ṣalaye fun BBC News Yoruba nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹ pe Alufaa ijọ naa, Pasitọ Anifowoṣe ati Igbakeji rẹ, Josiah Peter Asumosa “sọ fun awọn ọmọ ijọ naa pe Jesu yoo pada de ni oṣu kẹrin ọdun 2022, ki o to tun yii pada lati sọ pe o ti di oṣu kẹsan an ọdun 2022, ti o si sọ fun awọn ọdọ inu ijọ naa lati maṣe gbọran si awọn obi wọn lẹnu mọ, ati pe awọn obi wọn ninu oluwa nikan ni ki wọn maa gbọ ọrọ si lẹnu.”












