Cultural Burial: Ìdí táwọn ènìyàn South Korea ṣe ń sin èèyàn láàyè!

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O le ni eto isinku eniyan ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn ti ile isinku Hyowon Healing Centre ti ṣe fawọn eniyan lààyè!
Igbesẹ akọkọ fun ilana eto isinku awọn eniyan ti wọn ṣi wa laaye ti wọn ko tii ku ni pe ẹni naa a kọkọ ṣe akọsilẹ iwe ipingun rẹ to ṣafihan bo ṣe fẹ ki wọn pin ogun oun.
Lẹyin eyi o maa sanwo to yẹ nile isinku to wuu lati ṣeto isinku rẹ nigba ti ọlọjọ ba de.
Orilẹ-ede South Korea ni aṣa yii ti wọpọ julọ.
Iru ẹni bẹẹ maa tun ra irufẹ posi to wuu ki wọn fi sin oun si lẹyin to ba papoda.
O maa wa sun sinu posi yii fun nkan bii iṣẹju mẹwaa o kere tan.
Choi Jin-Kyu to jẹ akẹkọọ to ṣẹṣẹ pe ọmọ ọdun mejidinlọgbọn to ti kopa ninu eto isinku alaaye yii ṣalaye fawọn akọroyin pe oun ṣee nitori pe gbogbo eeyan n ṣee ni.
- Wọ́n ti ṣí aṣọ lójú eégún àwọn ọmọ Boko Haram tó sá kúrò ní Kuje
- 'Gbogbo àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Sofiat ló ṣì wà ní àhámọ́'
- Wo àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà yan olórí ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative mìíràn ní UK
- Olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní Japan, Shinzo Abe dágbére fáyé
- Ìfẹ̀hónúhàn bẹ̀rẹ̀ ní Owo lórí akẹ́kọ̀ọ́ Rufus Giwa Poly ti Amotekun ṣèèṣì pa
Choi ni pe oun ṣẹ nitori oun maa to bẹrẹ iṣẹ ati pe oun fẹ ki ọkan oun balẹ pe oun ti ṣe nkan to yẹ ni ṣiṣe.
Ojọgbọn Yu Eun-sil to jẹ dokita to n ṣayẹwo iku to pa eniyan ni o ṣe pataki fawọn ọdọ lati mọ sii nipa iku ki wọn si ṣeto to yẹ.
Ojọgbọn yii to ti kọ iwe loriṣiirisi nipa iku ẹda ni ko si ohun to buru ninu ki eeyan musilẹ de ọjọ iku rẹ.
Ogbeni Jeong Yong-mun to ni ileeṣẹ Hyowon ni inu oun maa n dun ti awọn eniyan ba n forijin oku ṣugbọn o san lati foirjin ara wọn nigba ti ẹni naa ba ṣi wa laaye nitori o ti le pẹ ju nigba mii lẹyin iku.
O tun ni igbese yii maa n yi ero awọn miran ti wọn ronu lati pa ara wọn pada si daadaa.
- Iléeṣẹ́ ológun òfurufú ṣèèṣì ju àdó olóró sí abúlé kan ní Katsina, eèyàn 14 farapa
- A ó parí pápákọ̀ òfúrufú ìpínlẹ̀ Ekiti kí n tó parí sáà mi- Fayemi
- Àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ní Ghana, ìjọba ṣetán láti gbọ́ ti wọn
- Ẹ̀yin òbí, ẹ má kó àwọn ọmọ yín lọ síbùdó atúnwàṣe mọ́ - Seyi Makinde
- Gbọ̀ nkán tí Ooni ní àwọn oríadé yóò fí tí INEC lẹ́yìn lórí ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tó wọlè dé...-
















