Ibadan Torture House: Seyi Makinde ní gbogbo ẹni tó mú èèyàn nígbèkùn ní yóò kojú òfin

Gomina ṣebẹwo si ile amuni nigbekun Ibadan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kilọ fun awọn obi ki wọn dẹkun kiko ọmọ lọ si awọn ile ti wọn n pe ni ibudo atunwaṣe ṣugbọn to jẹ pe ọtọ la n gbọ nipa wọn.

Nigba ti Gomina Seyi Makinde ṣe abẹwo si ile Ọlọrẹ to wa ni adugbo Ọjọọ nilu Ibadan, tii ṣe ibi ti ile imuni nigbekun ọhun wa, o pasẹ pe ki wọn wo Mọsalasi ọhun patapata.

Gomina ni "ohun taa ti ri jẹ nkan ti gbogbo wa gbudọ bu ẹnu atẹ lu ni ko si yẹ ko maa ṣẹlẹ lode oni. Ẹ o le maa fi mọṣalaṣi ṣe iru iṣẹ ibi bayii".

Àkọlé fídíò, Ibadan Torture House:Àṣírí ilé ìmúni nígbèkùn míràn tú síta ni Katsina
Bayii ni ile imuni nigbekun Ibadan ṣe ri

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Ile amuni nigbekun Ibadan

Oríṣun àwòrán, @seyimakinde

Makinde ni awọn ti ṣaami si ile naa fun wiwo, ijọba yoo si ṣe ohun to yẹ lati ri i pe iru iwa ibajẹ yii ohun itan lawujọ wa.

O ni ṣugbọn bi awọn to n gbe lagbegbe yii naa ba ri ohun ti ko tọ bi eleyii, o yẹ ki wọn sọ fun awọn alaṣẹ tọrọ kan, "a ko ba si ti ri aṣiri rẹ lọjọ to ti pẹ".

"Bakan naa, a fẹ gba awọn eeyan wa, obi ati ẹbi nimọran pe bi ẹ ba tilẹ fẹ ki iyipada ba aye awọn eeyan yin ti ko huwa daadaa, a ni awọn ile iṣẹ ijba to n moju to eyi fun ipinlẹ Oyo".

Ile amuni nigbekun Ibadan

Oríṣun àwòrán, @seyimakinde

Seyi Makinde ni o yẹ ki a maa mu ofin ilu ẹni lọkunkundun taa ba fẹ ṣe iru nkan bayii, o si jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹ laabi yii ni yoo foju wina ofin.

Ni ti awọn ti wọn tu silẹ nigbekun, Seyi Makinde ni awọn ti gbe iṣẹ le ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọ́n obinrin nipinlẹ Oyo lọwọ, lati ṣetọju wọn ati lati wa ọna ati da wọn pada sọdọ ẹbi wọn, "tori a o le fi wọn silẹ bayii".

"A gbudọ de kulẹ kulẹ ọrọ yii, awọn agbofinro yoo ṣe iṣẹ wọn de bi iwadii ao si tu ẹni tọwọ rẹ ba mọ silẹ". Eyi lọrọ ti gomina Seyi Makinde fi silẹ.