Ọwọ́ ṣìnkún NDLEA tẹ obìnrin tó yí igbó mọ́ ọsẹ dúdú àti kànìn-kànìn

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Ọwọ palaba arabinrin kan ti segi nigba to n gbiyanju lati gbe oogun oloro fawọ́n arinrinsjo meji to n lọ si orileede Oman lati papakọ ofurufu Murtala Muhammed nilu Eko.
Ajọ to n gbogun ti okoowo, ilo ati mimu oogun oloro, NDLEA lo fi ikede yi sita lati ọwọ agbẹnusọ wọn, Femi Babafemi.
Gẹgẹ bi alaye rẹ, Opoola Mujidat yi igbo sinu igba ọṣẹ dudu ati anin-kanin, to si gbe fun awọn arinrinajo meji kan.
Awọn arinrinajo naa ni Raji Babatunde Kazeem ati Akinbobola Ominiyi pe ki wọn ba oun fi jiṣẹ fun ọkọ oun ni Oman.
Mujidat di igbo mọ inu igba to gbe ọṣẹ dudu si
Ajọ Ndlea sọ pe awọn oṣiṣẹ awọn to ṣe ayẹwo ẹru ti awọn arinrinajo meji yii gbe lọwọ lo jẹ ki akara tu sepo.
Babafemi to jẹ alukoro ajọ yi ni awọn arinrinajo naa ke gbajare pe ẹni to gbe ẹru ti wọn ko igba pamọ sinu rẹ fawọn, ko ti lọ jina ati pe o ṣi wa ninu papakọ ofurufu.
Kia lawọn oṣiṣẹ ajọ yi wa Mujidat ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn yi kan, ti o si jẹwọ pe lootọ loun gbe ẹru naa le awọn arakunrin ọhun lọwọ.
O sọ pe ọkọ oun to wa ni Oman ni oun ni ki wọn gbe ẹru naa le lọwọ bi wọn ba de ilẹ naa.
Inu igba to ko ọṣẹ dudu si lo yi igbo yi mọ, to si gbe sinu apo ounjẹ ti ọkan ninu awọn arinrinajo yi fẹ gbe lọwọ lọ si Oman.
Ajọ Ndlea ko sọ boya awọn arakunrin yi ati Mujidat jọ n ṣiṣẹ pọ ni.
























