Ada Ameh, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà kú lẹ́yìn ọdún méjì tí ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Ada Ameh/Instagram
Gbajugbaja oṣere tiata, Ada Ameh lo ti jade laye lana ọjọ Aiku ni ile iwọsan kan ni ipinlẹ Delta.
Ameh ni wọn lo jẹ alejo nibi ayẹyẹ kan ileeṣẹ kan to risi ipese epo bentiro.
Ibi ayẹyẹ naa lo su bu, ti o si dero ile iwosan Nigerian National Petroleum Corporation’s hospital
Sugbọn aisan lo se wo, a ko ri ti ọlọjọ se, ẹlẹmi ti pari isẹ rẹ lara osere tiata naa.
Ẹgbẹ awọn osere tiata fidi iku Adah Ameh mulẹ:
Aarẹ ẹgbẹ awọn osere tiata nilẹ wa, Emeka Rollas ti wa fidi iku gbajumọ osere tiata yii mulẹ fun BBC.
Amọ o ni oun ko tii le sọ pato ohun to fa iku osere binrin naa.
Iku Adah si lo waye lẹyin ọdun keji ti ọmọ kansoso to bi jade laye.
Osu Kẹwa ọdun 2020 ni Aladi Godgift Ameh dero ọrun, ti osere tiata naa ko si ni ọmọ laye mọ.

Oríṣun àwòrán, Ada Ameh/Instagram
Kókó márùn-ún nípa àgbà òṣeré, Ada Ameh
Ada Ameh jẹ oṣere tiata Nollywood ti a bi ni ọjọ kẹẹdogun ọdun 1974.
O wa lati ilu Idoma ni ipinlẹ Benue sugbọn wọn bi ni Ajegunle ni ipinlẹ Eko.
O ka ile ẹkọ akọbẹrẹ ati girama rẹ ni ipinlẹ Eko sugbọn o dẹkun lati ma lọ ile eko lẹni ọdun mẹrinla.
O darapo mọ ẹgbẹ tiata lọdun mẹtadinlọgbọn sẹyin.
Ameh ti kopa ninu ọniruru sinima sugbọn eyi to gbe saye ni “Domitilla” lọdun 1996.
O wa lara awọn oṣere to wa ninu gbajugbaja fiimu ‘The Johnson’ lori Africa Magic.
Osere tiata Ada Ameh padanu ọmọ rẹ kan soso, ẹni ọdun mẹrinla lọdun 2020 .
















