Sri Lanka yan ààrẹ tuntun lẹ́yìn tí ààrẹ tẹ́lẹ̀ sálọ lásìkò ìwọ́de aráàlú

Ṣé ààrẹ tuntun ní Sri Lanka yóò mú ìrẹ́pọ̀ wá bí?

Ranil Wickremesinghe

Awọn asofin orilẹede Sri Lanka ti yan olootu ijọba, Ranil Wickremesinghe gẹgẹ bii aarẹ tuntun fun orilẹede naa.

Wickremesinghe yii ni yoo maa koju isẹ bi yoo se mu orilẹede naa kuro ninu ọfin ọrọ aje to dagun, eyi to jin si.

Igbesẹ naa lo waye lẹyin ifẹhonu han alagbara to waye lati ọdọ araalu fun ọpọlọpọ osu.

Aarẹ tẹlẹ ni ilẹ Sri Lanka, Gotabaya Rajapaksa si ti sa kuro lorilẹede naa lọsẹ to kọja.

Orilẹede Maldives lo kọkọ morile, ko to rekọja lọ si Singapore lẹyin ti ẹgbẹlẹgbẹ araalu jade sita lati se iwọde.

Awọn olufẹhonuhan naa lo ya wọ ilegbe aarẹ, atawọn ileesẹ ijọba miran, ti wọn si n beere pe ki aarẹ kọwe fipo silẹ.

Bakan naa ni wọn n beere pe ki Wickremesinghe, ti wọn yan sipo olootu ijọba losu Karun ọdun yii, kọwe fipo rẹ silẹ.

Awọn oluwọde naa lo jo ile adani aarẹ, ti wọn si tun lọ ka mọ ọọfisi to n lo bii olootu ijọba, eyi to wa ni Colombo lati se iwọde tako ilana isejọba rẹ.

Amọ awọn oluwọde naa ni o di dandan ki olootu ijọba naa lọ lẹyn ti aarẹ Gotabaya Rajapaksa kọwe fipo silẹ.

Awọn oluwọde ni Sri Lanka

Ipenija nla ni Olootu ijọba naa n koju lati ọdọ Dullas Alahapperuma, tii se asofin kan lati inu ẹgbẹ to n se isejọba lọwọ amọ ti ẹgbẹ alatako gboogi nilẹ naa, n se atilẹyin fun lati di aarẹ.

Aarẹ Wickremesinghe ni yoo pari saa isejọba Rajapaksa, eyi ti yoo wa sopin losu Kọkanla ọdun 2024.

Orilede Sri Lanka lo ti jẹ gbese pupọ, to si tun n koju ọwọn gogo ounjẹ, epo bẹntirolu atawọn ohun eelo amayedẹrun miran.