Kò fẹ̀ẹ́ sí ọ̀dọ́ Ṣagamu tí kìí ṣé omọ ẹgbẹ́ òkùnkùn-Alukoro Ọlọ́pàá Adejobi

Aworan alukoro agba ileese ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Facebook Olumuyiwa Adejobi

Alukoro agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria Muyiwa Adejobi ti da sí ọrọ to n lọ lóde nipa awon ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Shagamu to si sọ pe ko fẹẹ si ọdọ ilu yi ti kii ṣe ọmọ ẹgbẹ okunkun.

Loju opo Twitter rẹ táa tun mọ si X lo ti sọ ọrọ yi to sì ni ọrọ to da òun l'oju ni pé bẹẹ lọ se ri nípa awọn ọdọ ilu yi.

Adejobi sọ pe ati olokada ati awọn akẹkọọ to fi mọ awọn oniṣẹ ọwọ ni wọn wá ninu ẹgbẹ okunkun.

Nígbà tí eeyan kan koju rẹ pe ọrọ yi wuwo lẹnu o ni nkan to da òun l'oju ni pé àwọn ọdọ ilu Shagamu a maa ṣe ẹgbẹ okunkun .

O ní ọrọ Shagamu kii ṣe ajoji sí oun.

"Ẹ beere lọwọ wọn tí wọn kò bá mọ mi.Ko so eni to wa lati Shagamu tí yoo sọ pé ọrọ ti mo sọ ko ti bẹẹ.Tori náà ma bẹru nípa nkan ti ko sọ.Koda awọn agbalagba ati ọmọ ilu mọ pé bẹẹ lo ri''

Lafikun, o ní àwọn araata mii naa a maa wa sí Shagamu lati wa da wahala ija ẹgbẹ okunkun silẹ.

O tọka sí àwọn ọmọ ilu Edo wí pé àwon naa a maa wa sí Shagamu wa kópa nínú ija ọmọ ẹgbẹ okunkun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun míì ní Shagamu

Lori ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Shagamu yi kanna ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun sọ pé àwọn tí mú afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje.

Atẹjade ti wọn fí soju opo X sọ pe ikọlu tàwọn ọlọpaa ṣe sí awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun waye nígbà tí iroyin ikọlu tó waye laarin awọn ìkọ Aiye ati Ẹiyẹ De sí eti igbọ wọn.

Nínú ikọlu awọn afurasi yi ni wọn tí sọ pé eeyan merin ku ni Ewu Iya Sunday, Sakura.

Ọlọpaa láwọn rí ọta ibọn ati awọn nkan ija olóró gba lọwọ awọn afurasi méje yi ṣugbọn okan ninu wọn ribi sa mọ awọn agbofinro lọwọ.