Wo kókó ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ níbi àpérò àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé

Oríṣun àwòrán, TINUBU/X
Ààrẹ Bola Tinubu ti ní àsìkò ti tó fún ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti gòkè àgbà àti ṣe ìdádúrò bí àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà ṣe ń jí àwọn ohun ìní ẹkùn Adúláwọ̀.
Tinubu sọ èyí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi àpérò àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé tó wáyé ní New York.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Tinubu ní àsìkò ti tó fún àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé láti ṣe àmúṣẹ àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń sọ nípa ríri dájú pé àwọn tó ń jí ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ Adúláwọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèrè ni wọ́n mú balẹ̀.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè ló ti di aṣálẹ̀ látàrí ìwàkùsà lọ́nà àìtọ́ tó ń wáyé níbẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo ni ó ti ń wà nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn pẹ̀lú bí àjọ UN ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà tó.
Ààrẹ ní ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé ló jẹ́ DR Congo ní nǹkan tó pọ̀ àmọ́ tí wọ́n ń fun ní ohun kékeré.
"Ọ̀pọ̀ àwọn ará ilẹ̀ òkèrè ni wọ́n ń lo àwọn ọmọ ìlú láti sọ wọ́n di ẹrú láti máa jí wúrà wà.
Ó ní tí wọn kò bá tètè mójútó àwọn nǹkan yìí yóò túnbọ̀ máa dúnkokò àlàáfíà àti ètò ààbò tó sì ń sọ àwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀ sínú ewu.
"Àwọn orílẹ̀ èdè tí ọ̀rọ̀ kàn gbọ́dọ̀ kún wa lọ́wọ́ láti gbógunti àwọn iléeṣẹ́ àtàwọn ọmọ ìlú láti dènà ìwà olè jíjà lọ́nà ìgbàlódé yìí."
Tinubu wòye pé ìṣẹ́ òhun òṣì gbọ́dọ̀ di ohun ìgbàgbé, bí àwọn orílẹ̀ èdè ńlá ṣe ń jí àwọn nǹkan àlùmọ́ọ́nì lọ sí orílẹ̀ èdè wọn.
Ó fi kun pé Nàìjíríà ti ṣetán fún ìdókoòwò láti jí ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Ó kọminú pé ohun tó jẹ́ ìbéèrè ni pé ṣé àwọn orílẹ̀ èdè yìí ti ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Nàìjíríà àti orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ lápapọ̀.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìpalára tí àyípadà ojú ọjọ́ ń kó bá àwọn orílẹ̀ èdè, ó ní àwọn orílẹ̀ èdè gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ tí yóò ṣe àǹfàní fún orílẹ̀ èdè wọn.
Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti mú kí ayé dùn ún gbé fún gbogbo orílẹ̀ èdè.















