Ọjọ́ mẹ́rin láàrin ọ̀sẹ̀ ni Buhari fi ń lọ sóko lẹ́yìn tó kúrò nípò Ààrẹ - Garba Shehu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Muhammadu Buhari
Amugbalẹgbẹ aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buahari ti safihan igbesi aye ọga rẹ lẹyin ọgọrun ọjọ to kuro ni ori ipo Aarẹ.
Garba Shehu salaye ninu atẹjade to fi sita to pe orukọ rẹ ni "Ọgọrun ọjọ ti Buhari kuro nipo Aarẹ", o ni pe ọjọ mẹrin laarin ọsẹ ni Buhari fi n lọ si oko niluu Daura.
O ni Buhari pinnu lati lọ si Daura nitori ko fẹ duro si ilu Abuja lati fun ijọba tuntun laaye ati ireti pe ti oun ba ji na, oun yoo ni isimi.
“Buhari ma lọ si oko rẹ fun ọjọ mẹrin laarin ọsẹ kan, to si mujuto ohun ọgbin ati awọn ohun isin rẹ.
“O n gba isimi to yẹ sugbọn abẹwo awọn eeyan si i ni a ko ri da duro.”
Shehu ni Aarẹ tẹlẹ n gba alejo awọn eeka ilu si ile rẹ niluu Daura lojojumọ.
Bakan naa, Garba Shehu bu ẹnu atẹlu bi awọn eeyan kan ṣe kọ lati gbe oriyin fun awọn aṣeyọri Buhari lasiko to wa ni ijọba.
“A ko ti ri igun kan ti iṣejọba Buhari ko mu ọwọ ba. A ri ọpọlọpọ iyatọ laarin ọdun mẹjọ to wa ni ijọba sugbọn awọn eeeyan n pirọrọ lati ma sọ otitọ ọrọ.
“A mọ pe awọn eeyan kan yoo si ma tako iṣejọba Buhari
“Aarẹ Tinubu jẹ oloye oloṣelu yoo ri awọn eeyan to da nnkan boju yi.
“Mohammdu Buhari ti ṣe ti rẹ o si ti kuro, itan ko le gbagebe rẹ ati pe itan yoo tun ṣe idajọ.”












