Kí ló ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú Xenophobic attack lorílẹ̀-èdè South Africa?

Àkọlé fídíò, Kí ló ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú Xenophobic lorílẹ̀èdè South Africa?

Ikọ fijilante Operation Dudula lorilẹede lo ti da ọpọlọpọ wahala silẹ lẹyin ti wọn ṣe ikọlu si awọn okowo awọn ajoji, ti wọn si fipa ti ilẹkun sọọbu wọn. BBC Africa Eye se iwadi lori isẹlẹ naa ati bi awọn ọmọ ẹgbẹ ikọ naa ṣe n sisẹ.

Ninu ile idana ilẹ ẹkọ ni Kwa Theme, ilu to wa ni ila oorun Joshannesburg, Dimakatso Makoena ti n ṣe Sandwich.

Obinrin ẹni ọdun mẹtadinlọgọfa lo jẹ obinrin to n dagbe pẹlu ọmọ mẹta, to si ti n sisẹ nibẹ fun ọdun mẹfa.

Bi o ṣe n sọrọ pẹlu omije, o ni; “Lotitọ mo korira awọn ajoji . O wumi ki wọn ko gbogbo ẹru wọn kuro lorilẹede wa.

A ko mọ bi ikorira yii ṣe to ka to ba Ms Makoena to gbe ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ , to si fi aworan ọmọ rẹ to n se aisan , ti apa si wa lara rẹ pẹlu oju rẹ to pọn.

Aworan igbe araalu kan

O ni, ”o bẹrẹ si ma lo ologun oloro nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹrinla” O salaye pe o bẹrẹ si ni ma jale lati jẹun. Lọjọ kan o fẹ ji ina gbena wọle Transformer lati lọ ta ti ina si gbe, to si tun jona pẹlu.”

Ọmọ rẹ lo ti mọ lara lati ma lo ologun oloro, to si n da gbogbo agbegbe laamu lorilẹede South Africa.

Gbogbo lo da le lori pe Obinrin yii da awọn ajeji to n ta ogun oloro, to si n ṣe atilẹyin fun ikọlu Operation Dudula

O sọ fun BBC pe, “Dudula nikan lo mu mi tẹsiwaju.”

Ọdun meji sẹyin ni Soweto ni Operation Dudula, to si jẹ ikọ akọkọ to n se ikọlu ‘Xenophobic’ lorilẹede South Africa. Awọn ikọlu yii bẹrẹ kete ti ijọba alawọ funfun wa sopin lọdun 1994. Wọn pe arawọn ikọlu to n gbe ogun ti awọn ajeji, Dudula tumọ si ‘Kuro ni agbegbe wa’ ni ede Zulu.