Kìí ṣe irú àsìkò yìí ló yẹ kí Sanwo Olu fòpin sí ẹ̀dínwó owó ọkọ̀- aráàlú Èkó ké gbàjarè

Aworan ọkọ akero Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ikede ti ijọba ipinlẹ Eko fi sita lori mimu opin ba eto ẹdinwo owo ọkọ faraalu ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn gbadun eto naa lasiko to fi waye, ni awọn mii sọ pe ijọba ko ṣe daadaa bi wọn ṣe fẹ mu opin ba nkan to mu ayedẹrun lasiko ti nkan ko rọgbọ faraalu.

Loju opo Twitter (X) taa ti ṣe agbeyẹwo esi to ba ikede yi wa, o dabi ẹni pe inu ọpọ ko dun si mimu opin ba ẹdinwo owo ọkọ tí araalu n jẹ anfaani yi.

Pupọ lo fẹ ki ijọba ipinlẹ Eko to ṣe agbekalẹ rẹ yi ero pada ki wọn si tẹ sí iwaju pẹlu rẹ.

Nigba wo ni ẹdinwo yi yoo wa si opin ?

Gẹgẹ bi atẹjade ti ijọba ipinlẹ Eko fi sita lati ọwọ ẹka rẹ to n seto irinkerindo ọkọ taa mọ si Lamata ṣe sọ, ọjọ Aiku ọsẹ yi lo wa sopin.

Wọn ni "ọjọ Aiku ni eto ẹdinwo ida aadọta taa ṣe l'awọn ọkọ wa to n na awọn agbegbe kan ni Èkó yoo wa sopin"

Wọn fikun pe bẹrẹ lati ọjọ Aje tii ṣe ọjọ Kẹfa owo ọkọ yoo pada sí bo ṣe wa ṣaaju ikede ẹdinwo.

Ọjọ keji oṣu kẹjọ ọdun 2023 ni ìjọba Gomina Babajide Sanwo Olu kede adinku owo ọkọ gẹgẹ bi ọna ati mu idẹkun ba araalu lẹyin ti ijọba apapọ kede pe ko ni sí ẹdinwo owo epo bẹntiroolu taa mọ si subsidy.

Lara awọn nkan t'awọn ijọba ipinlẹ ṣe ni eto ẹdinwo owó ọkọ fawọn araalu.

Ipinlẹ Eko nikan kọ lo gbe iru igbesẹ yi amọ a ko yi ti rí ikede lati awọn ipinlẹ mi pe awọn fẹ mu opin ba ẹdinwo owo ọkọ tàwọn gbe kalẹ.

Ipinlẹ Kwara, Oyo ati Borno wa lara awọn taa mọ pe wọn gbe iru eto yi kalẹ ti wọn o si ti mu opin ba.

Kini gbajare araalu si ijọba lori ọrọ yii?

Loju opo ti ikede yi ti waye ko jọ bi ìgbà tí awọn eeyan kan n rawọ ẹbẹ si ìjọba pe ki wọn wo ọrọ ẹdinwo owo ọkọ yi ṣe fún araalu.

Lara ọrọ ti eeyan kan fi ṣọwọ ni ìdáhùn sí ikede ìjọba o ni awọn ko tiẹ tii gbadun ẹdinwo yi ki ijọba to dawọ rẹ duro.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Koda awọn kan sọ pe kaka ki wọn da owo ọkọ pada si iye to wa ki ẹdinwo to gun nise ni owo ọkọ tun le sí.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3