Ọwọ́ Ọlọ́pàá tún tẹ Alfa míì pẹ̀lú orí èèyàn àti apá èèyàn méjì n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Oyo Police
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo safihan ọkunrin kan, to n pe ara rẹ ni Alfa pẹlu ori eeyan ati apa eeyan meji niluu Ibadan.
Ninu atẹjade ti Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso fi ransẹ si awọn akọroyin, o ni ọwọ tẹ afurasi naa lọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun 2023.
Hassan Kolawole, ẹni ọdun marundinlaadọta ni ọwọ tẹ ni agbegbe Ogbere-Tioya nijọba ibilẹ Ọna Ara, ti wọn si ka ori eeyan ati apa eeyan meji to ni Tijani Waheed kan lo gbe fun oun.
Awọn mii wo ni ọlọpaa tun mu?
Ileeṣẹ Ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ lati sawari Waheed Tijani, ẹni ti wọn ni pe o ti salọ bayii.
Waheed ni Alfa Hassan sọ pe o gbe ori ati apa eeyan naa fun oun.
Bakan ni wọn tun safihan awọn afurasi adigunjale, ti wọn tun jẹ afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun.
Wọn ka egboogi olooro, ibọn ati ada oloju meji mọ lọwọ.
Ọwọ tẹ awọn afurasi adigunjale yii lọjọ kejilelogun ni agbegbe Apata niluu Ibadan












