Ilé-ẹjọ́ kọ ẹ̀bẹ̀ àwọn Ọyọmesi lórí ẹjọ́ tí wọ́n pe Gómìnà Mákindé

Alaafin Lamidi Adeyemi

Lẹẹkan si i, ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ọyọ ti kọ ẹbẹ apa kan awọn Ọyọmesi ti wọn ni ki Gomina Ṣeyi Makinde ma ṣe da si iyansipo Alaafin Ọyọ tuntun.

Awọn olupẹjọ to gbe Gomina Makinde ati Olootu eto idajọ nipilẹ Ọyọ, pẹlu kọmiṣanna fun ọrọ oye jijẹ nipinlẹ naa lọ si kootu ni : Yusuf Layinka (Baṣọrun Ọyọ), Wakeel Oyedepo (Lagunna Ọyọ), Amusa Yusuf (Akinniku Ọyọ) Wahab Oyetunji (Areago Baṣọrun) ati Gbadebọ Mufutau to jẹ Alapo Ọyọ.

Awon Ọyọmesi ti wọn ti kọkọ pe ẹjọ naa tẹlẹ, sọ fun kootu pe awọn ko fẹ ki gomina atawọn eeyan rẹ lọwọ ninu iyansipo Alaafin Ọyọ, nigba to jẹ awọn gẹgẹ bi Afọbaje ti n gbe igbesẹ to yẹ lati ọdọ awọn.

Nigba to n kọ ẹbẹ awọn olupẹjọ naa l’ Ọjọbọ ọsẹ yii , Adajọ Ladiran Akintọla sọ ọ di mimọ fun agbẹjọro awọn olupẹjọ, Kazeem Ṣọbaloju pẹlu awọn Ọyọmesi, pe oun ko le gba ẹbẹ wọn naa wọle.

Adajọ Akintọla sọ pe ohun to yẹ ni lati jẹ ki Gomina atawọn yooku ti wọn pe lẹjọ naa sọ tiwọn labẹ ofin, eyi ti yoo ṣalaye idi ti wọn fi n tako igbesẹ awọn Afọbaje.

O ni nigba naa lofin faaye silẹ lati jẹ ki idajọ to wa nilẹ lori ẹjọ yii fẹsẹ mulẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ninu igbẹjọ to waye lọjọ kọkalelọgbọn oṣu kẹwaa ,ni Ṣọbaloju ti kọkọ gbe ẹbẹ kan naa siwaju ile-ẹjọ, ṣugbọn Adajọ da a nu, o si sun igbẹjọ mi-in si ọjọ keji oṣu kọkanla.

Lọjọ igbẹjọ naa, Amofin Ṣọbaloju fi to kootu leti pe awọn ko ni i tẹsiwaju lori ẹjọ ọhun mọ, awọn yoo pe omi-in ni.

Ṣaa, igbẹjọ tuntun lori ẹjọ yii di ọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun yii